Brexit: Boris Johnson ṣèlérí láti mú UK kúrò ní àjọ̀ ìṣọ̀kan Gẹ̀ẹ́sì tiku-tiye

Boris Johnson Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Boris Johnson ní òun yóò mú UK kúrò ní àjọ̀ ìṣọ̀kan Gẹ̀ẹ́sì tiku-tiye

Ni kete ti gbogbo pọpọsinsin ba pari lori iyansipo Olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi, ọkan lara awọn ipenija nla nidi oselu ilu ọba ni Boris Johnson yoo kọkọ koju, eyi to nii se pẹlu bi ilẹ Gẹẹsi yoo se kuro ninu ajọ isọkan ilẹ Yuroopu laisi afẹnuko kan gboogi.

Ki wa ni itumọ "Brexit ti ko ni adehun ninu" ati ohun to duro fun?

Ki ni itumọ Brexit ti ko ni adehun ninu?

Niwọn igba ti ko ti si adehun ti wọn yoo fẹnu ko le lori, ilẹ Gẹẹsi yoo kuro ninu ajọ isọkan ilẹ Yuroopu ni kiamọsa lai se adehun kankan lori ọna ti igbesẹ lilọ wọn yoo da le lori.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lọsan kan, oru kan, UK yoo kuro ni ọja kansoso alajumọse ati asa nini ajọsepọ - eto ti wọn gbe kalẹ lati dokoowo papọ laarin awọn orilẹede to wa labẹ isọkan ilẹ Yuroopu, ti ko si ni lọwọ ayẹwo ọja abi sisan owo ori ninu.

Bakan naa ni ko ni adehun ninu tun tumọ si pe, lọgan ti ilẹ Gẹẹsi ba fi ajọ isọkan ilẹ Yuroopu silẹ, naa ni yoo kuro ninu awọn ajọ to wa labẹ rẹ bii ileẹjọ apapọ fun ilẹ Yuroopu ati ileesẹ agbofinro apapọ wọn taa mọ si Europol.

Ko tan sibẹ, opin yoo tun de ba bi ilẹ Gẹẹsi se jẹ ọmọ ẹgbẹ awọn ajọ nlanla to jẹ ẹka ajọ isọkan ilẹ Yuroopu to n se agbekalẹ ati amojuto ilana to rọ mọ oogun titi de idamọ wọn.

UK ko tun ni maa da owo sinu eto isuna ajọ isọkan ilẹ Yuroopu mọ - eyi to jẹ biliọnu mẹsan pọun, eyiun biliọnu mọkanla ati miliọnu lọna ẹgbẹrun meji dọla ($11.2BN) lọdun.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Lọsan kan, osu kan ni UK yoo kuro ninu ajọ isọkan ilẹ Yuroopu, ti wọn ko ba fi ẹnu ọrọ jona titi di ọjọ Kọkanlelọgbọn osu Kẹ́wa ọdun 2019

N jẹ o seese lati yago fun?

Labẹ adehun ti ijọba Theresa May se - eyi ti ile asofin apapọ wọgile ni ẹẹmẹta ọtọọtọ - ilẹ Gẹẹsi ko ba wọnu eto ilana olosu mọkanlelogun ti wọn yoo tọ kuro ninu ajọ isọkan ilẹ Yuroopu.

Eyi ko ba fun wọn ni akoko, lati duro sipo ti ohun gbogbo wa na, nigba ti igun mejeeji ba n jiroro lori ọna to tọ lati pinya.

Amọ nibayii, ti ijsba fẹ lo ilana kikuro ninu ajọ isọkan ilẹ Yuroopu lai lọwọ adehun ninu, awọn asofin apapọ yoo fontẹ lu aba to n beere fun ilana yiyapa lati sọ di ofin, bakan naa ni wọn yoo beere afikun ọjọ ti wọn yoo kuro lọwọ ajọ isọkan ilẹ Yuroopu tabi ki wọn wọgile igbesẹ yiyapa kuro ninu ajọ ọhun patapata.

Lẹyin tawọn asofin apapọ kẹyin si adehun ti May se, ọjọ Kọkanlelọgbọn osu Kẹwa ọdun 2019 ni gbedeke ọjọ ti ilk Gẹẹsi ni mọ lati yẹra kuro ninu ajọ isọkan ilẹ Yuroopu patapata.

Iha wo wa ni Boris Johnson kọ si ilana kikuro ninu ajọ isọkan ilẹ Yuroopu laini adehun ninu?

Boris Johnson ti seleri lati mu UK kuro ninu ajọ isọkan ilẹ Yuroopu nipari osu Kẹwa ọdun yii ni "tiku-tiye."

Lasiko ifọrọwerọ kan lori redio nigba to n polongo lati jẹ asaaju fun ẹgbẹ oselu rẹ, Conservative Party - eyi ti yoo sọ di Olootu ijọba ilẹ Europe logan - Boris ni "A ti n gbaradi lati jade lọjọ kọkanlelọgbọn osu kẹwa. Ko si iru ohunkohun to wu, to lee sẹlẹ."

Nigba ti wọn bi pe ko fi idi ọrọ yii mulẹ, o fikun pe: "Tiku-tiye. Ko si iru ohunkohun to wu, to lee sẹlẹ."

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọpọ awọn eeyan to faramọ pe ki ilẹ Gẹẹsi kuro ninu ajọ isọkan apapọ Yuroopu gbagbọ pe, awọn ko ni pẹ bori ipenija to lee yọju lori ọrọ aje ti Gẹẹsi ba kuro laisi adehun kankan

O ni oun yoo wọgile adehun kikuro ti Theresa May se, ti oun yoo si beere fun ilana adehun miran to yatọ patapata ko to di ọjọ kọkanlelọgbọn osu Kẹwa, nitori ayipada ranpẹ ko lee tẹ oun lọrun. "A nilo ilana adehun tuntun pe a fẹ yọwọ-yọsẹ."

Aarẹ tuntun ti wọn sẹsẹ dibo yan fun ajọ to n ri si akoso awọn orilẹede nilẹ Yuroopu, Ursula von der Leyen - ti yoo gba ọpa asẹ lọjọ kinni, osu Kọkanla ọdun 2019 - tun ti tẹnumọ ipinnu ajọ isọkan ilẹ Yuroopu lori ọrọ yii.

Image copyright EPA
Àkọlé àwòrán Ajọ to n ri si akoso awọn orilẹede nilẹ Yuroopu yoo ni Kọmisana tuntun, Ursula von der Leyen, lati ọjọ kinni, osu Kọkanla

O ni oun yoo se atilẹyin fun afikun ọjọ ti ilẹ Gẹẹsi yoo kuro ninu ajọ isọkan ilẹ Yuroopu, amọ o ni awọn ko ni tun se idunadura mọ lori ilana adehun ti ilẹ Gẹẹsi yoo gba kuro ninu ajọ naa.

Ilana lilọ wọn naa lo sọ pe yoo nira pupọ - amọ ile asofin apapọ ilẹ Gẹẹsi lo si wa lẹnu isinmi lọwọ lọwọ bayii.