Nigeria Election: Kò sí ìwé ìrìnnà 'VISA' fáwọn ọmọ Naijiria tó hùwà àìtọ́ nígbà ìdìbò

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán A ko ni fun oniṣẹ ibi ni iwe irinna Amerika

Ilẹ Amerika ti fi ofin de fifun awọn oniṣẹ ibi lasiko idibo Naijiria ni iwe irinna.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ Amerika, Morgan Ortagus lo ṣo eyi di mimọ ninu atẹjade to fi sita ni Washington lorilẹ-ede Amerika.

O ni ofin tuntun yii ko yọ awọn ti wọn gbiyanju lati da idibo Naijiria tọdun 2019 to kọja yii rú silẹ.

Ortagus ṣalaye pe lati ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kinni ọdun ni Amerika ti n gbiyannju lati gbe igbesẹ yii paapaa lori awọn oloṣelu ti ko fẹ ilọsiwaju eto oṣelu.

Titi di asiko yii, ilẹ Amerika ko tii gbe orukọ àwọn ti ọrọ naa kan sita fun araye lati ri.

Tabi ki wọn ṣafihan awọn ilana aatẹle ti wọn fẹ fi ṣawari awọn ti wọn ṣe magomago lasiko idibo ọhun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionHubert Ogunde ló m'órí mi yá láti di òṣèré

Koko pataki ti Ortagus tun sọ ni pe awọn ti ọrọ kan jẹ awọn ti wọn n hu iwa Tani-o-mumi, ti wọn ko bọwọ fun ẹtọ ọmoniyan rara.

Image copyright others
Àkọlé àwòrán Kò sí ìwé ìrìnnà 'VISA' fáwọn ọmọ Naijiria tó hùwà àìtọ́ nígbà ìdìbò

Agbenusọ ilẹ Amerika ni ofin yii kii ṣe fun gbogbo ọmọ Naijiria rara bikoṣe fun awọn to huwa ipa lasiko idibo to kọja nikan.

Lati igba ti Naijiria ti fẹ dibo tọdun 2015 ni ilẹ Amerika ti n kilọ fawọn oloṣelu lati ṣọra fun iwa aitọ.

Wọn ni awọn ti ṣetan lati rii pe wọn gbe igbesẹ yii ki onikaluku le kọ ẹkọ to yẹ ninu iwa ọmọluwabi lasiko idibo.

Olubadamọran nigba kan ri fun ileeṣẹ Amerika sọ fun BBC pe ipinnu ilẹ Amerika lasiko yii fihan pe ko si ajọṣepọ to fẹ dan mọran laarin ijọba Buhari ati ileeṣẹ Amerika to wa ni Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIbadan Accident: Èèyàn méjì kú, ẹnìkan wà nílé ìwòsàn