Ṣé irúfẹ́ oúnjẹ tí ò ń jẹ́ lè jẹ́ kí o gbádùn ìbálòpọ̀ rẹ síi?

lọkọlaya Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán ọpọlọpọ gbagbọ pe arogun n mu lọkọlaya gbadun ara wọn daadaa

Ko si ẹri pé oriṣi ounjẹ kan ṣoṣo n mu ibalopọ dun laarin ololufẹ.

Ounje to kun fun gbogbo eroja aṣaraloore, igbe aye alaafia ati ọpọlọ to ji pipe a maa mu eniyan gbadun ibalopọ daadaa.

O ni awọn ounjẹ ti o maa n ṣafikun eroja ìmúfẹ̀ẹ́ laarin ololufẹ meji ti wọn ti fidiẹ mulẹ pe o nii ṣe pẹlu owo ati aṣeyọri.

Wo awọn ìtàn ati imọ sayẹnsi to rọ mọ awọn ounjẹ ti a gba pe o n fi kun adun ibalopọ.

Awọn kan gba pé jijẹ ìṣẹ́pe inú odò n ṣiṣẹ́:

Casanova ti itan gba pe o gbadun ibalopọ ju ni wọn ni o maa n jẹ to iṣẹpẹ aadọta laraarọ

Bẹẹ ko si iwadii to fidi ẹ mulẹ pe iṣẹpẹ ti Casanova n jẹ gẹgẹ bii ounjẹ aarọ rẹ lo n mu u ki ara rẹ maa figba gbogbo dide.

Awọn kan tun n sọ pe Aphrodite to jẹ oriṣa ifẹ ni a bi lati inu ododo ifẹ ati foomu funfun ninu odo ni eyi to fi jẹ pe awọn ohun abẹmi inu odo maa n mu ki adun ifẹ pọ sii.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán ọrọ ifẹ bii adanwo ni

Iwadii fihan pe eroja síǹkì maa n jẹ ki nkan ọmọ ọkunrin le sii ki àtọ̀ ọkunrin si pọ sii.

Awọn ounjẹ to n ṣafikun síǹkì lara ni ẹja onipẹ, ara ẹran, eso, kaṣuu, eréè, miliki ati wara.

Awọn miran gbagbọ pe jijẹ Ṣokoleeti dudu tabi to ti jona diẹ maa n fi kun adùn ibalopọ:

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn onimọ sayẹnsi ni jijẹ ṣokoleeti dudu yoo jẹ ki ina ifẹ romjo sii

Ọpọlọpọ lo gbagbọ pe ti awọn ba n jẹ ṣokoleeti ti o jẹ ohun adidun lati inu kòkó maa n jẹ ki ololufẹ meji tubọ gbadun ara wọn sii.

Iwadii fihan pe o ni eroja ifẹ ti wọn npe ni Phenylethylamine (PEA).

PEA ni eroja to maa n mu ki ifẹ ko si ololufẹ meji ti wọn ṣẹṣẹ bẹrẹ ọrọ ifẹ wọn lori. Eyi maa n jẹ ki apa ọpọlọ wọn to n mu ki ifẹ gbooro ji pepe sii.

Eyi tun maa n jẹ ki agbara adun ibalopọ pọ sii ni eyi ti iwadii fihan pe diẹ lo wa ninu ṣokoleeti.

Iwadii tun fihan pe eroja Amino Acid Tryptophan to wa ninu koko a maa mu inu ẹni dun sii laini idi pataki kankan ni pato.

Ni nkan bii ẹgbẹrun ọdun pupọ sẹyin ni Hernán Cortés to jẹ onimọ ọmọ Spain gbajọba ẹkun ti a n pe ni Mexico nsiyi lọwọ Maya Ati Aztec.

Oun ni ara Yuroopu akọkọ to kọ nipa ṣokoleeti.

O kọwe si Oba rẹ pe oun kẹfin pe awọnMaya ti wọn n mu koko a maa ni okun ati agbara ti kii fi rẹ wọn pupọ.

Ati pe ko si ẹri to fidiẹ mulẹ pe awọn Castali ti Maya n fi ṣokoleeti mu nkan ọmọ ọkunrin wọn le sii lasiko naa.

Awọn eroja ounjẹ ti a ti le ri tryptothan to n mu adun ifẹ dun sii ni ẹyin, adiyẹ, ewedu, eso ati soya.

Ṣé jíjẹ ata le mu adun balopọ rẹ pọ sii?

Iwadii ti fihan pe ata ni eroja Capsaicin to maa n jẹ ki aṣaraloore endorphines pọ sii lara eniyan.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ata jijẹ maa n jẹ ki ara ji pipe ni

Endorphins yii wa lara awọn nkan to maa n mu inu eniyan dun ti ọkan yoo si gbe soke.

Imọran pataki ni pe ki o ranti fọ ọwọ rẹ daadaa ti o ba ti fi ọwọ kan ata nitori ata kii ṣe ọrẹ oju.

Ati pe Yoruba gba pe ẹmi ti ko jẹ ata, ẹmi yẹpẹrẹ ni.

Njẹ o mọ̀ boya mimu ọti maa n fikun adun ibalopọ laarin ololufẹ meji?

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Oti lile le jẹ ki ara rẹ gbe

Ọti mimu a maa ṣafikun si adun ibalopọ nitori pe o maa n mu itiju kuro loju ololufẹ ni.

Macbeth nigba ti o ti mu ọti yo tan ni: ọti lile n mu ibalopọ wu ni ṣugbọn kii jẹ ki eeyan le ta pútú dáadáa.

Awọn tọkunrin tobinrin paapaa a maa ni amojukuro ti wọn ba ti mu ọti lile ni eyi to maa n din asiko ibalopọ ku tabi ki eeyan ma lè ṣe mọ to ba ya.

Ni afikun, ki eeyan maa run bii ile ọti kii mu adun ifẹ pọ.

Wo bi o ṣe le mu ara rẹ ji pepe sii fun ibalopọ:

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Fi ọkan rẹ sinu adun ti o fẹ gbadun pẹlu ololufẹ re.

Iwadii ti fidiẹ mulẹ pe jijẹ awọn ounjẹ to kun fun Flavonoids ti o n jade lara ewebẹ a maa dena nkan ọmọkunrin ti ko ṣiṣẹ daadaa.

Jijẹ eso pupọ loriṣiriṣii bii ọsan, ibẹpẹ, ọpẹ oyinbo, ọgẹdẹ ọmini a maa fi kun agbara lasiko ibalopọ sii.


Ṣiṣe ere idaraya naa a maa din aileṣe daadaa lori ibusun ku ni ida mẹrinla si mọkanlelogun ninu ọgọrun un.

Iwadii fihan pe lilo ilana Mediterrania to n polongo jijẹ eso, ewebẹ, ẹfọ loriṣiiriṣi, girepu, kabeeji, ẹwa ati awùsá a maa fun tọkunrin tobinrin ni agbara sii lasiko ibaraẹnilopọ.

Fun idi eyi, maa jẹ eso loriṣiiriṣii daadaa.

Wo ohun to yẹ koo mọ sii nipa awọn eroja amu-adun ibalopọ pọ sii lori ibusun:

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Oriṣa Aphrodite ti wọn tun n pe ni Venus to wa lati inu odo ti nkan adun ifẹ ti jade

Ona mẹta ni a le pin awọn nkan adun ibalopọ yii si gẹgẹ bi iṣẹ won lara.

A ni eyi to n mu inu ẹni dun ki iṣẹ le ya lori ibusun, a tun ni eyi to n jẹ ki àtọ̀ pọ sii lara ati eyi to n mu ni gbadun ifẹ ẹni.

Ko si eyi ti iwadii tii ṣafihan odiwọn iṣe won ni ara eeyan ninu imọ sayẹnsi.

Lara eṣinṣin eso nikan ni iwadii tii fi mulẹ pe wọn ti n ṣiṣẹ daadaa.


Dokita Krychman to jẹ onimọ nipa ilera ibalopọ ni oun gba pe awọn eeyan n jẹ eroja ifẹ nitori pe o ti ṣiṣe fun ẹlomii ri ni.

Opo ninu awọn eroja ibalopọ yii jẹ ounjẹ aṣaraloore ti wọn wulo fun ara.

Imọran wa pe ki a sá fun ewe ti wọn ko tii ṣe iwadii lori rẹ tabi awọn gbogbo niṣe ti ko ni ẹri.

Imọran:

Ti o ba fura pe o ko gbadun ibalopọ bii ti tẹlẹ, lọ kan si dokita rẹ fun itọju to pe ye.