Dokita yọ góòlù kílò kan àtààbọ̀ àti owó ṣílè nínú obìnrin kan

goolu
Àkọlé àwòrán,

Igba wo ni goolu di ounjẹ nikun eeyan?

Goolu kilo kan ati aabọ ni awọn dokita yọ ninu obinrin kan ti wọn ṣiṣẹ abẹ fun ni India.

Ni kete ti iya ọmọbinrin yii ṣe kẹfin pe ọdọbinrin naa n figba gbogbo bì ni o ba gbe e lọ sile iwosan fun ayẹwo.

Ṣaaju asiko yii ni iya rẹ ti fura pe ojoojumọ ni nkan bii ohun ẹṣọ ohun n sọnu ninu ile.

Bi wọn ti gbe ọmọbinri yii de ile iwosan naa lo tun ti n bi ti wọn fi sare gbe e lọ ṣe iṣẹ abẹ fun un.

Iya ọmọ yii ṣalaye pe o ti ṣe diẹ ti ọmọ oun ti n ni arun ọpọlọ to ti n farahan diẹdiẹ sẹyin.

O ni nkan bii oṣu meji ni awọn ti n ṣọ ọ nitori pe o dabi ẹni pe oogun ti wọn n lo fun un ko ṣiṣẹ bi o ti yẹ.

Nigba ti wọn pari iṣẹ abẹ naa ni awọn dokita rii pe ọpọlọpọ owó ṣile ni wọn ko sita ninu ọmọbinrin naa ati goolu ti iwọn rẹ tó kilo kan ati abo giraamu.

Àkọlé fídíò,

Yorùbá gbà pé òrìṣà bí ìyá kò sí!

Siddharatha Biswas to jẹ ọga agba ile iwosan Rampurthat Government Medical College ti wọn ti ṣe iṣẹ abẹ naa ni owọ ṣile aadọrun un ni awọn yọ sita ninu ikun rẹ.

Àkọlé fídíò,

Sri Lanka áti India níkan ni irù ològbó yì wá

Dokita naa ni awọn ri ẹgba ọrun, goolu imu, yẹti eti, ẹgba ọwọ, goolu ẹsẹ, aago ọwọ ati awọn nkan miran ni wọn ko yọ.

Àkọlé fídíò,

Ajọ SERAP sọrọ lori owo ifẹhinti awọn oloselu kan

Nigba ti wọn n beere ọrọ lọwọ ọmọbinrin ti ọrọ kan yii lo ni ti ebi ba n pa oun ni oun maa n jẹ nkan ki nkan ti oun ba ri.

Awọn dokita ni wọn ti bẹrẹ itọju arun ọpọlọ fun ọdọmọbinrin naa.