Ìjọba Nàìjíríà ti ṣẹ́gun Boko Haram- Ààrẹ Muhammadu Buhari

Ààrẹ Buhari
Àkọlé àwòrán Jẹjẹrẹ ní ìwà àlákakiti ẹ̀sìn, ẹ yago fún ẹ̀kọ́ òdì -Ààrẹ Buhari

Ààrẹ Muhammadu Buhari ti ke sí àwọn ọmọ Nàìjíríà pé ọ̀rọ̀ Boko Haram lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí di àfìẹ́yìn tí éégún ń fisọ pàápàá jùlọ gbogbo ǹkan ìjà òògun wọn ti tán tí àwọn ọmọogun si ti tú wan ka pátápátá.

Ààrẹ ni wọ́n kò ní agbára láti gba ìlú kankan lórilẹ̀-èdè Nàìjíríà dé bi ti wọ́n yóò ni àànfani láti ta àsíà tàbi dúkoko mọ́ ẹnikẹni ju wákàtí mẹ́rìnlélógun lọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionYollywood: Sinimá Ajé Ọjà tún so Fathia àti Saheed Balogun pọ̀ nínú Sinimá

Ààrẹ sọ èyí di mímọ lọ́sàn òní lórí àtẹjíṣẹ́ Twitter rẹ̀, ó fi kún pé bi ìjọba ṣe ń rọkun sápa àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí wọ́n sí ń fún wọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó yẹ, tí ìjọba kò si ṣe à[rẹ lóri mímú ìwúri ba àwọn ọmọ ologun, o ti di dandan ki wọn ṣe àṣeyọri.

O fí kun pé ìjọba to n bẹ lóde kò ni káàrẹ nínú dídabò bo àwọn ọmọ Nàìjíríà lábẹ́ àkóso bóti wù kórí, ìjọba yóò dàyà àwọn ẹni ibi bolẹ̀.

Ààrẹ Buhari sàlàyé pé, "ọ̀rọ̀ ìdánilóju yìí kìí ṣe lóri ọ̀rọ̀ Boko Haram nìkan bíkóse ti ìjínigbe àti àwọn ìwà ìbàjẹ míràn, a ò ni gbọ̀jẹ̀gẹ́ titi tí à ó fi fa gbogbo àwọn oniṣe ibi tu ni orilẹ̀-èdè

Ẹwẹ̀, ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà ló tí ń fẹ̀sì si ọ̀rọ̀ ààrẹ lóri Twitter bákan náà

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKayeefi: Facebook ni Wolii Arole Jesu fi tàn an wọ agbo, orí rẹ̀ ni wọ́n fi s'owó