Army Vs Police: Ẹ gbọdọ wẹ́ orúkọ ilé iṣẹ́ ọmọ ogun mọ́ kúrò nínú ọ̀rọ̀ yìí- Buratai

military Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Army Vs Police: Ẹ gbọdọ wẹ́ orúkọ ilé iṣẹ́ ọmọ ogun mọ́ kúrò nínú ọ̀rọ̀ yìí- Buratai

Olú ilé iṣẹ́ àwọn ọmọ ogun ti pàṣẹ fún 93 Battalion tó wà ní Takum, ìpínlẹ̀ Taraba láti sàwári ọ̀daràn Hamisu Wadume tó sá mọ́wọn lọ́wọ́ láti yọ ilé-iṣẹ́ ọmọogun kurò nínú ẹrẹ̀ tí wan wà yìí àti láti dúró bí ẹlẹ́ri pe kò si ọwọ́ àwọn ọmọ ogun ninu ìwà ìbàjẹ́.

Alhaji Hamisu Wadume sálọ lásikò ti ọlapàá àti àwọn ọmọ ogun fija pẹ́ẹta ti ọlọpàá mẹ́ta àti àárá ìlú méji ti gbẹ̀mi mì ní Ibi, ìpiínlẹ̀ Taraba, lọ́jọ́ Iṣẹ́gun tó kọjá.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKílò fa èdè àìyedè láàrin ìjọba àti àwọn ọmọ lẹ́yìn El-Zakzaky?

Ọgá àgbà kan tí kò fẹ́ ki a dárukọ lásìkò tó ba akọròyìn Punch sọ̀rọ̀ sàlàyé pé ọgá àgbà pátápátá ti dári 93 Battalion láti sàwári ọ̀daràn náà, ó fi kún pé ìgbìmọ̀ tí wọ́n gbé kalẹ̀ láti ṣe ìwádìí ọ̀rọ̀ náà le ma ṣe ǹkankan to nitumọ àfi ti ọdún iléyá bá pari.

O sàlàyé ilé iṣẹ́ ọmọ ogun ko ní sàì yọ ẹnikẹ́ni ti ìgbà ọ̀rọ̀ náà ba si mọ lóri níṣẹ́ pẹ̀lú ìjìyà tó tọ́ sí irú ẹní bẹ́ẹ̀ àti gbogbo àwọn ti wọ́n jọ sowọ́ pọ̀.

Ìwádìí fi hàn pé ilé iṣẹ ọmọogun kò ti ṣàbẹ̀wò si Tàrábà nígbà ti àwọn ọlọpàá ti débẹ, sùgban adelé olùdari ìgóhùn sáfẹ́fẹ́ fún ilé iṣẹ́ ọmọogun Col. Onyema Nwachukwu sàlàyé pé ìgbìmọ ti ilé iṣẹ́ ọmọ ogun gbé kalẹ̀ ń tẹ̀lé ìlànà gẹ́gk bi ààrẹ ṣe pàṣẹ.

Àwọn òṣìṣẹ́ ẹká ọtẹ̀lẹ̀múyẹ́ ni ilé iṣk ọlọpàá lọ fún iṣẹ́ ìdákọ́nkọ́ kan ti ASP Felix Adolije sááju wọ́n, ni [wan ti ni ìdóju kọ pẹ̀lú àwọn ọmọogun Nàìjíríà ní òpópónà Ibi-Jalingo lásìkò ti wọ́n gbé ogbóntarigi ajínígbé Hamisu Wadume lọ si olú ilé iṣe ọlọpaa kan ni Jalingo.

Image copyright Policeng
Àkọlé àwòrán Army Vs Police: Ẹ ṣe àwárí ọdànran tó bọ mọ́yin lọ́wọ́ - Turkur Buratai

Ọlọ́pàá mẹ́ta ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà rìn Mark Ediale, Usman Danzuni àti Dahiru Musa.