Oúnjẹ àràmọ̀ǹdà mọ́kànlá tí wọ́n ń jẹ lágbààyé rèé, ẹ tẹ́wọ́ gbàá

Frogs Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Turkey n fi omi ara ọpọlọ ti wọn ti rẹ se ara rindin

Ounjẹ jijẹ jẹ ọrẹ ara, amọ jijẹ idin ninu burẹdi jẹ ohun to so si ni lẹnu, to si bu iyọ si.

Bayii ni ọrọ ri fun awọn to n gbe agbeegbe Sardinia ni orilẹede Italy, ti wọn fi idin se ounjẹ ajẹpọnnula, ti wọn yoo si dupẹ lọwọ ẹnikẹni to ba fun wọn ni burẹdi onidin jẹ.

Eyi lo mu ki wọn pinnu lati se afihan ile ounjẹ ti ko wọpọ lawujọ si awọn gbagede kan, eleyii to bẹrẹ ni Malmo, lorilẹede Sweden ni Ọjọ Kọkanlelọgbọn, Osu Kẹwa, ọdun 2018.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Sise afihan ounjẹ yii yoo fi agbara fun ero awọn eniyan wi pe, ohun to kọju si ẹnikan, ẹyin lo kọ si ẹlomiran.

Ẹ wo oúnjẹ àràmàndà 11 tí wọ́n ń jẹ lágbààyé

Yoruba bọ wọn ni bayii lati n se ni ilẹ wa, eewọ ibomiran ni.

Eyi lo mu ki onimọ nipa ihuwasi ati ise ọmọniyan, Samuel West sọ wi pe, ounjẹ jijẹ jẹ ohun abalaye to n se afihan ihuwasi eniyan ati ibi ti eniyan ti ṣan wa.

Orilẹede Italy ma n jẹ burẹdi ati iyẹfun ti wọn fi idin se:

Image copyright Anja Barte Telin
Àkọlé àwòrán Jijẹ burẹdi onidin jẹ eewọ nilẹ Europe nitori ipa rẹ lara awọn eniyan.

China: Ni orilẹede China, wọn ma n jẹ oko akọ maluu. Awọn onimọ ni ki Obinrin o jẹ funfun, nigbati Ọkunrin yoo jẹ dudu rẹ.

Image copyright Anja Barte Telin
Àkọlé àwòrán Orisirisi ounjẹ aramanda lo wa ni China.

Uganda: Tata ni ounjẹ awọn ara Uganda, eleyii ti wọn ti yii lata. Wọn a ma jẹ ẹ pẹlu ọti waini.

Amọ eewọ ni fun awọn obinrin oloyun, ki wọn ma ba a bi ọmọ ti ọpọ́n ori rẹ yoo jọ ti tata.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Uganda n fi ati waini lo tata ti wọn ti yi lata.

Mexico: Ounjẹ ati papanu ni ẹyin kokoro jẹ lorilẹede Mexico. Wọn ma n din, ti wọn si ma n gbadun rẹ lọpọ igba.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Hmmn... ẹyin kokoro naa ko gbẹyin ninu ounjẹ amaradan.

Vietnam: Ọkan ejo Sèbé ni awọn eniyan ma fi n se ounjẹ jẹ. Wọn ni o ma n fi agbara kun agbara wọn.

Wọn si le e jẹ ọkan ejo naa pẹlu ẹjẹ ejo tabi oti waini Vodka.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán N jẹ o ti jẹ ọkan ejo ri?

Awọn ara orilẹede Iran, Afghanistan ati Iraq ko fi oju abo àgbò sere rara ati ọpọlọ rẹ. Gbogbo rẹ ni jijẹ fun wọn.

Wọn ni kii jẹ ki eniyan wuwo lalẹ to ba fẹ sun.

Ilẹ Gẹẹsi:Ounjẹ aarọ to peleke ni ki eniyan o fi ẹjẹ ẹlẹdẹ ti wọn ti sè, kun ounjẹ to fẹ jẹ lojumọ.

Ounjẹ owurọ ko i tii pe ni Ilẹ Gẹẹsi ti ko ba si ẹjẹ ẹranko ti wọn ti se nibẹ. Wọn ni o dara fun eroja asaraloore iron, zinc ati protein.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ounje aarọ re e ni Ilẹ Gẹẹsi.

Peru: Omi ara ọpọlọ ti wọn ti rẹ ni awọn fi n se ara rindin, ti wọn si tun n ta a fun awọn eniyan gẹgẹbi omi ẹlẹrindodo to n mu araji pepe.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Turkey n fi omi ara ọpọlọ ti wọn ti rẹ se ara rindin

Ohun to wọpọ ni orilẹede Turkey ni lati fi igba aya ati ọmu akukọ se ounjẹ jijẹ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Turkey n jẹ igba aya ati ọmu akukọ.

Orilẹede China: Eleyii ya ni lẹnu pupọ ju. Orilẹede China a ma a fi ekute ile se ọti waini ẹlẹrin dodo.

Amọ awọn ekute yii gbọdọ jẹ eyi ti wọn sẹsẹ bi, ti ko i ti pẹ ju nilẹ. Wọn ni o ma n sisẹ fun aisan ikọfe e ati aisan jẹdọjẹdọ.

Image copyright Mo Styles
Àkọlé àwòrán China a ma a fi ekutele se oti waini ẹlẹrin dodo.

Ni Russia: Ko buruju ti wọn ba fi omi ara ẹja to n sere ibalopọ se ọbẹ ti wọn yoo jẹ.

Moloka ni wọn n pe orukọ ounjẹ naa. Orilẹede Japan naa a ma a jẹ ounjẹ yii.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ni Russia, awọn eniyan n jẹ omi ara ẹja lasiko ti wọn ba n lopọ fi se ọbẹ ẹja.

Ẹ ri pe awọn ounjẹ aramọnda pọ lorilẹ aye, ewo ni ẹyin fẹ ko jẹ ninu wọn?