Brexit: UK fẹ́ so ìjókòó ilé rọ̀, kíni èyí túmọ̀ sí?

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Brexit nibo ni ọrọ yii maa ja si fun UK

Laarọ ọjọru ni alakoso Britain tuntun, Boris Johnson gbe igbesẹ lati so ijokoo ile rọ.

Igbesẹ yii to ba di mimuṣẹ tumọ si pe gbendeke ti awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin a ni lati fi jiroro lori bi UK a ṣe yọ kuro ni Brexit a tun dinku sii ni.

Ogbeni Boris Johnson n gbero ki ipade ile bẹrẹ pada ni ọjọ kẹrinla, oṣu kẹwaa ọdun.

Eyi tumọ si pa kaka ki wọn lọ si isinmi asiko yii, o di ọjọ kẹwaa, oṣu kẹsan an ki wọn to le lọ.

Image copyright EPA
Àkọlé àwòrán Bi ko si ẹwa ko le si gbẹgiri, bi ile ko jokoo ko si imuṣẹ ofin

Ohun to n kọnilominu lori isinmi awọn ọmọ ile igbimọ aṣofiin yii ni pe Ogbẹni Johnson n din odiwọn akoko ijokoo ile ku ni.

Eyi si ti jẹ ki awọn oloṣelu kan lori ariyanjiyan lori igbesẹ Brexit ni eyi to lọwọ kan ejo ninu.

Agbẹnusọ ile, John Bercow ni ko si orukọ meji fun igbesẹ yii ju "aibọwọ fun ofin" lọ.

Agbẹnusọ ti gbogbo eeyan gba pe kii figba gbogbo sọrọ lori oṣelu naa ni ohun to wu ki Boris wi; igbesẹ isinmi lasiko yii jẹ ọna lati dina ijiroro lori Brexit nile igbimọ aṣofin ni.

Image copyright @uk
Àkọlé àwòrán Ti a bá so ijokoo ile rọ̀ ki lo lè ṣẹlẹ?

Jeremy Corbyn to jẹ olori ẹgbẹ Labour naa ni ko si aaye rara fun Boris lati so ijokoo ile rọ lasiko yii.

O ni eyi tako ominira to yẹ ko wa ati pe o dabi igba ti eeyan ba fẹ fipa gba nkan lọwọ ẹlomii ni.

Kinni sisio ijokoo ilé rọ̀ tumọ si?

Ijokoo ile ko ṣee deede so rọ laijẹ pe Adari orilẹ-ede (Boris Johnson) gba Obabinrin Elizabeth nimọran lati ṣe bẹẹ.

Awọn ọmọ ile igbimo a maa lọ fun isinmi atigbadegba ṣugbọn ko gbọdọ jẹ lasiko ti o mu ifura dani bi eyi.

Odun kan ni awọn ọmọ ile igbimọ fi maa n jokoo ṣugbọn ti eyi to n lọ lọwọ yii ti bẹrẹ lati oṣu kẹfa, ọdun 2017 to ti fẹẹ pe ọdun meji bayii.

Kete ti wọn ba ti so ijokoo ile rọ ko ni si ijiroro tabi idibo kankan.

Awọn abadofin ti wọn ko ba fẹnuko le lori ti wọn fi so ijokoo rọ yoo lọ soko igbagbe ni.

Ti wọn ba gba igbesẹ Boris yii wọle, o tumọ si pe ko ni si ijokoo ile fun ọjọ iṣẹ mẹtalelogun ni UK.

Igbesẹ Boris yii ṣeeṣẹ ko tẹ awọn ololufẹ ẹ lọrun ṣugbọn o nii ṣe pẹlu ileri rẹ lati yọ kuro ni Brexit titi oṣu kẹwaa ọdun.

Image copyright PA Media
Àkọlé àwòrán Boris ko le da so ijokoo ile rọ lai kàn si Obabinrin Elizabeth

Kinni o wa máa ṣẹlẹ bayii ni UK?

O di dandan ki awọn ọmọ ile igbimọ kọkọ ṣi jokoo ni ọjọ Iṣẹgun to m bọ ki wọn to bẹrẹ isinmi ti ẹnu ba kò.

Ti erongba Boris Johnson ba ṣẹ, o di ọjọ kẹrinla, oṣu kẹwaa ki wọn to tun jokoo pada.

O ṣeeṣe ki wọn dibo gbogboogbo loṣu kẹwaa ti awọn ọmọ ile ba dibo jẹwọ ara rẹ ni oṣu késan an ọdun.

Lara awọn ileri ti Boris Johnson ṣe ṣaaju idibo ni pe oun ṣetan lati fi ẹmi oun wa ojutu si ọrọ Brexit.

Bayii, ọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Conservative ni mo fẹ kuro ni Brexit laijẹ pe erongba wọn wa si imuṣẹ.

Ẹru n ba wọn lori eto ọrọ aje ilẹ Britiko ati ọwọngogo nkan ti erongba wọn ko ba ṣẹ.

Image copyright EPA
Àkọlé àwòrán Mo ṣetan lati fi ẹmi mi wa ojutu si ọrọ Brexit - Boris

Boris Johnson kede pe Obabinrin a ba awọn eniyan sọrọ ni ọjọ kẹrinla, oṣu kẹwaa dun ki awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin to bẹrẹ ijokoo ile pada.

Iwọde to ti n waye lori ikede siso ijokoo ile rọ:

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awa ko faramọ igbesẹ Boris yii nia riwo ti wọn mu bọ ẹnu

Lọjọru ni awọn eniyan bẹrẹ iwọde niwaju English parliarment ni Westminster.

Ariwo pe awọn ko fẹ igbesẹ igbọjẹgẹ Boris ni wọn n pa.

Wọn gab asia ilẹ European Union ati ti UK.

Wọn si ṣeleri lati tubọ ṣe iwọde titi Boris a fi gbọ ohun ti wọn n fẹ.

O ti le ni miliọnu kan awọn eniyan ti wọn ti buwọlu iwe iwọde lodi si igbesẹ Boris Johnson larin ọjọ kan ti wọn bẹrẹ.