UK students Phone ban: A fẹ́ bẹ̀rẹ̀ òfin má lo fóònù mọ́ fàwọn ọmọ wa -Òbí

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ẹ dẹ́kun lílo èrò ibanisọrọ lasiko yii

A fẹ ki ẹ fi ofin de ki awọn akẹkọọ maa lo ẹrọ ibanisọrọ - Obi ni UK

Iṣẹ iwadii kan ti wọn ṣe ni United Kingdom lo fi erongba awọn obi ati alagbatọ hande lori ki awọn ọmọ maa lo ẹro ibanisọrọ nile iwe.

Iwadii naa to waye laarin obi ati alagbatọ ẹgbẹrun kan ni o ṣafihan pe ida mọkandinlaadọta obi ko faramọ lilo ẹrọ alagbeka ibanisọrọ nile iwe.

Matt Hancock tó jẹ akọwe nipa ọrọ aṣa ni o ya oun lẹnu lati ri awọn ile iwe ti wọn ti n fofin de lilo foonu nile iwe.

Opium ni o ṣeto iṣẹ iwadii naa lorukọ USwitch ni United Kingdom.

Iṣẹ iwadii yii gbero pe to ba maa fi di ọdun 2019, gbogbo ẹrọ ibanisọrọ ti awọn eeyan yoo maa lo ni UK a ti to biiliọnu meji le ni ọọdunrun pọun.

Ernest Doku to jẹ akọṣẹmọṣẹ USwitch ni odiwọn iye ẹrọ alagbeka ti ti awọn akẹkọọ yii n muwa sile iwe kọja bẹẹ.

Bakan naa lo ti hande pe ida mẹtalelogoji ninu awọn ọdọmọde akẹkọọ wọnyi ni wọn n lo ẹya ẹrọ alagbeka ti igbalode t awọn obi wọn ko ni lọwọ.

Odiwọn iye owo irufẹ ẹrọ ibanisọrọ ti wọn n lo yii kọ sisọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWo ọna ti o le gba lati fi daabo bo ara rẹ lori Facebook.

Abajade iwadii yii ko ya ni lẹnu pe awọn obi ati alagbatọ ko fẹ ki awọn ọmọ wọn lo ẹrọ ibanisọrọ mọ lasiko ti wọn ba wa nile iwe.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionScrabble: Yorúbà Scrabble ni àkọ́kọ́ ní èdè abínibí nílẹ̀ Afrika

Nitootọ lawọn obi ni lilo foonu nile iwe yii kii jé ki ọkan awọn akẹkọọ papọ si oju kan nibi ẹkọ wọn.

Ṣugbọn ọgbẹni Doku ni fifi ofin de ẹrọ ibanisọrọ kọ ni ọna abayọ loju toun si iṣoro yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌwà olè, jìbìtì àti ìjẹkújẹ ló n jé káwọn mii yí ọjọ́ orí wọn padà

Ogbẹni Doku ṣalaye pe ẹrọ ibanisọrọ wulo fawọn akẹkọọ ọdọmọde wọnyii nitori pe ọpọ obi lo maa fẹ mọ irin ẹsẹ wọn.

Ọpọ obi n fi ẹrọ ibanisọrọ beere irin ọmọ wọn ati ohunkohun to n ṣẹlẹ si wọn laisko ti wọn wa nile iwe ni eyi to n fi wọn lọkan balẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionObìnrin akunlé ìgbàlódé

Lọdun 2018 ni Aarẹ Eton ni ko yẹ ki ẹru ba obi ati ile iwe lati gba ẹrọ ibanisọrọ kuro lọwọ awọn ọmọ wọn.

O ni ko si ohun to buru ninu igbesẹ yii ṣugbọn kii ṣe gbogbo obi lo faramọ ọ.

Awọn obi ati alagbatọ kan gab pe nkan ti yipada ati pe ọmọde naa le lo ẹro ibanisọrọ nibikibi nigba to ba wuu.

Ojọgbọn Pail Howard-Jones to jẹ ogbontarigi ni Fasiti Bristol ni: O ṣe pataki ki ọmọ kọ nipa lilo ẹrọ ibanisọrọ lasiko to ba jẹ pe pataki iwe kika ni lati le gbe ninu aye pẹlu irọrun.

O ni o yẹ ki awọn ọmọde mọ ohun to yẹ ati eyi ti ko yẹ ni lilo ninu ẹro ibanisọrọ ti wọn ba gbe dani.