"Lẹ́yìn ọdún méjìlá, mo gun òkè fún ọjọ́ márùn-ún kí ń tó rí ìyá mi"
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ìwé kíkà ló pín ọmọ tálákà yìí àti àwọn òbí rẹ̀ níyà

Airin jinna ni airi abuke ọkẹrẹ, bii eeyan ba rin jinna, yoo kuku ri ibiti wọn ti n fi odo ibulẹ jẹun.

Ọmọkunrin kan ree, Jeewan, to gba ibiti ori daa si ni ori oke Himalayas lorilẹede Nepal tii se ilu abinibi rẹ, to si gbọdọ gun ori oke yii fun ọjọ marun ko to le fi oju kan awọn obi rẹ

Ọmọ ọdun marun si lo wa to fi jade lọ kawe ni Snowland nilu Kathmandu, lẹyin ọdun mejila to si n pada bọ wale, o nilo lati pọn oke naa pada fun odidi ọjọ marun, ko to de ilu wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Jeewan ni ipo ti oun ba ilu naa ati awọn obi oun ko dun mọ oun ninu bi o tilẹ jẹ pe inu wọn dun lati foju kan oun pada.

Ẹ wo bi irinajo ọmọkunrin naa se lọ ati ohun ti oju rẹ ri ko to de ilu wọn.