Adájọ yinbọn láti pá ará rẹ̀ lẹ́yìn tó bẹnu ẹ̀tẹ́ lù ẹ̀ka iṣèdájọ́

Aworan ẹka iṣedajọ
Àkọlé àwòrán Adájọ yinbọn pá ará rẹ̀ lẹ́yìn tó bẹnu ẹ̀tẹ́ lù ẹ̀ka iṣèdájọ́

Adajọ kan lorile-ede Thailand ti yinbọn pa ara rẹ ninu ile ẹjọ lẹyin to sọrọ nipa ṣiṣe deede lẹka iṣedajọ orile-ede naa.

Kanakorn Pianchana fi idajọ lelẹ lori ẹjọ kan to da pe awọn ọkunrin musulumi marun un kan ko jẹbi ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan wọn.

Lẹyin to dajọ naa tan lo pe fun iṣedeede lẹka iṣedajọ lorilẹ-ede Thailand.

Ni kete ti Adajọ Pianchana ka ẹjẹ awọn adajọ tan nile ẹjọ naa lo ba fabọn yọ sita ki o to yin in lu ara rẹ laya.

Ṣugbọn ori ko o yọ nitori wọn sare gbe e lọ si ile iwosan.

Lọwọlọwọ bayi o ti n gba itọju ni ile iwosan ni Thailand.

Ki lo ṣẹlẹ nile ẹjọ gan an?

Ni iwọ guusu Thailand ni adajọ yi ti n ṣiṣẹ nile ẹjọ kan lagbegbe ti a gbọ pe awọn ọmọ ogun ọlọtẹ ti n dara, ti wọn n ṣọṣẹ loriṣiiriṣi.

Lẹyin ti adajọ yii ni awọn ọkunrin marun un kan ko jẹbi nini nnkan ogun ija lọwọ lo ba awọn eeyan to wa ni ile ẹjọ sọrọ ti wọn si ṣafihan ọrọ rẹ loju opo Facebook Live.

Adajọ naa ni "Ẹri to daju gbodo wa ki o to le fiya jẹ ẹnikẹni. Bi ko ba si da o loju, ma ṣe fiya jẹ wọn''

"Mi o ni awọn eeyan marun un wọn yi ko jẹbi sugbọn o ṣe ṣe ki wọn jẹbi."

O salaye pe ''ilana idajọ gbọdọ má labawọn ninu ... ki eeyan ma ba fi iya jẹ alaiṣẹ''

Iran oju opo Facebook naa wa wa si opin lojiji lẹyin ti o ka ọrọ ibura awọn adajọ niwaju aworan aarẹ Thailand ki o to yinbọn lu ara rẹ laya.

Ki lo mu ki adajọ naa fẹ para rẹ?

Ko daju ohun to mu ki adajọ naa fẹ pa ara rẹ.

Suriyan Hongvilai, to jẹ agbẹnusọ fẹka idajọ sọ fun ileeṣẹ iroyin AFP pe ''iporuru ọkan lo mu u ṣe bẹẹ.''

Amọ awọn eeyan ni o ṣeeṣe ki o jẹ pe ẹjọ to da tan lo mu u yinbọn fẹ pa'ra rẹ.

Atẹjade kan ni pe adajọ naa fi ọrọ si oju opo Facebook rẹ nibi to ti ṣalaye pe awọn kan n dunkooko mọ oun lati dajọ ẹbi fawọn ọkunrin marun un naa tohun ti pe ko si ẹri pe wọn jẹbi.

Ohun ti adajọ naa sọ kẹyin ni pe ''Bi mi ko ba le pe ofin ipo ti mo di mu mọ, o san ki n kuku pa ara mi tọwọtọwọ''

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí