Àwọn ará ìlú so alàkóso ìlú ní Mexico mọ́ ọkọ̀, wọ́n sì wọ́ ọ káàkiri

Afihan CCTV nibi ti wn ti n fi ọkọ wọ alakoso ilu naa Image copyright Twitter/@tinta_fresca
Àkọlé àwòrán Aworan CCTV ṣafihan asiko tawọn eeyan n wọ alakoso abule naa nilẹ

Bi bata ba ti n ro kola kola, o ṣetan ti yoo ya ni.

Bẹẹ lọrọ ri nigba ti bata alakoso ilu kan ni Mexico ro kanla kanla titi tawọn ara ilu rẹ si da sẹria olorombo fun un latọwọ ara wọn.

A gbọ pe wọn so o mọ ọkọ ti wọn si wọ ọ nilẹ tuurutu lori titi laarin abule wọn.

Eeeyan mejila lawọn agbofinro ti mu lori iṣẹlẹ yii tawọn ọlọpaa si doola ẹmi alakoso abule naa Jorge Luis Escandón Hernández.

Igba 'keji ree ti awọn ara ilu yoo doju ija kọ alakoso naa ti wọn si ni ki o mu ileri rẹ ti o ṣe nipa titun oju ọna wọn kan to ti bajẹ ṣe.

Koda awọn ọlọpaa ti fi awọn agbofinro mii ranṣẹ si abule naa ni ipinlẹ Chiapas.

Lọpọ igba lawọn alakoso ati awọn oloṣelu ma n koju ikọlu lati ọwọ awọn janduku tori pe wọn kọ lati faaye silẹ fun wọn lati ṣẹ iṣẹ aburu wọn.

Ṣugbọn ko wọpọ ki awọn ara ilu maa doju ija kọ awọn alaokoso ti ko ba mu ileri wọn ṣẹ.

Ọgbẹni Escandón ni oun yoo pe awọn to ji i gbe naa lẹjọ lori ẹsun ijinigbe ati igbiyanju lati gbẹmi oun.

Fọnran fidio tawọn eeyan ya lati ṣafihan alakoso ilu naa bi awọn eeyan kan ṣe wọ ọ jade lati inu ọfiisi rẹ ti wọn si ju u sẹyin ọkọ.

Fidio naa re e.

Fidio miiran ti ẹrọ ayaworan CCTV ka ṣafihan ibi ti wọn ti so o mọ ọkọ ti wọn si n wọ ọ kiri oju ọna Santa Rita to wa lara agbegbe Las Margaritas.

Ọgọrọ awọn ọlọpaa lo gbiyanju lati da ọkọ naa duro ki wọn baa le doola ẹmi alakoso ọhun.

Awọn eeyan pupọ lo fara pa ninu ikọlu to waye laarin awọn ọlọpaa ati awọn to ji alakoso naa gbe.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu iṣẹlẹ kan to waye ni nnkan bi oṣu mẹrin sẹyin, awọn eeyan kan ya bo ọfiisi alakoso naa amọ wọn o ba a nibẹ.

Ṣaaju ki wọn to dibo to gbe ọgbẹni Escandón wọlẹ ni wọn mu oun gaan alara tori pe wọn lọ n ba awọn alatako rẹ kan wọ iya ija.

Wọn pada tu u silẹ tori pe awọn agbofinro lawọn ko ri ẹri aridaju pe o kopa ninu ikọlu naa.