America Serial Killer: Ìgbẹ̀yìn ọkùnrin tó pa obìnrin 93 ni America

Image copyright FBI
Àkọlé àwòrán Ajọ FBI ti fidi ọrọ yii mulẹ ni Amerika

Ajọ ọmọ ogun FBI ni america ni awọn mọọmọ gbe aworan awọn obinrin naa sita lasiko yii.

Awọn agbofinro ilẹ America ti mu Samuel Little to jẹ ọmọ ọdun mọkandinlọgọrin satimọle.

Won fi ẹsun ipaniyan aadọta kan Samuel Little pe o ṣe iku pa awọn obinrin mẹtalelaadọrun un laarin ọdun 1975 si ọdun 2005.

Lọdun 2012 ni ọwọ agbofinro tẹ Samuel pe o pa obinrin mẹta ki iwadii kikun to bẹrẹ.

Awọn ọlọpaa America fidiẹ mulẹ pe awọn obinrin alawọ dudu lo pọ ju ninu awọn ti ọkunrin yii ti ṣeku pa.

Samuel Little je afẹjẹkubiojo tẹlẹ jẹẹni ti ọpọ ero fẹran nigba to ṣi n kan ẹjẹ ni eyi ti ọpọ ko fi fura si i rara.

FBI ni wọn kọkọ gba pe aṣilo oogun lo pa awọn kan ninu wọn nitori awọn akọṣẹmọṣẹ FBI gbagbọ pe ootọ ọrọ lo n sọ.

Christie Palazzolo to jẹ akọṣẹmọṣẹ FBI ni: Fun ọpọlọpọ ọdun ni Samuel fi ro pe aṣiri oun bò nitori pe ọpọ ninu awọn to pa lo ro pe ko ni ẹbi ati ara to le ṣe iwadii iku wọn pupọ.

FBI ni ohun ni wọn ko fi fuu lara fun ọpọlọpọ ọdun ti wọn fi wa ṣe iwadii kikun lori ọrọ naa ni eyi ti wọn tun fi n ṣe iwadii iku awọn eniyan metalelogoji mii bayii.

Image copyright Wise County Jail
Àkọlé àwòrán Awọn alaṣẹ ni ọkunrin yii lo n jẹ Samuel Little to tun n pe ara rẹ ni Samuel McDowell

Awọn alaṣẹ ni Amerika ti gbe iroyin nipa iku awọn eniyan ni Kenturcky, Florida, Loisiana, Nevada, ati Arkansas ki wọn le mọ ohun to ṣeokunfa iku awọn eniyan ti wọn ko le fidi iku wọn mulẹ tẹlẹ.

Won tun fi awọran Little ninu ọgba ẹwọn sita ni eyi ti wọn gba pe o maa jẹ ki wọn ri ojutuu si ọrọ iku awọn miran.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKemi Lala: mo ń gbìyànjú láti mú inú òbí mi dùn

Little ti kọkọ jẹwọ nipa ṣiṣe apejuwe bo ṣe pade Marianne, Mary Ann ni Miami ni Florida ati bo ṣe tun pa ọdọbinrin ọmọ ọdun kan ninu oko ireke.

Bakan naa ni Little tun ṣapejuwe bo ṣe pa obinrin kan sile itura ni Las Vegas lọdun 1993.

O ni nigba ti oun pa obinrin naa tan ni oun sọ oku rẹ nu sinu koto kan.

Àkọlé àwòrán Maapu yii lo ṣafihan awọn agbegbe ti won fura pe Little ti pa awọn eeyan

Awọn agbofinro ni aile sọ akoko ni pato ti awọn iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ le ṣakoba fún iṣẹ iwadii naa.

Kenturcky ni wọn ti kọkọ mu Little ni 2012 ki wọn to gbe e lọ si Carifornia.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionInú mi dùn pé ọmọ obinrin nìkan ni mo bi

Little ti fipa ba obinrin lo pọ ri to tun ti jale kaakiri ilẹ America ki ọwọ too tẹ lẹyin ọpọlọpọ iwadii.

Bayii wọn ti gbe Little lọ si Criminal Investigations Program (ViCAP) to n ṣiṣẹ pẹlu awọn ọdaran ti wọn fipa ba lo pọ.

Bayii gbogbo iwadii awọn agbofinro ni wọn n to pọ lati le ṣe éjọ ọkunrin naa fun idajọ to yẹ fun un.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionDavid Adiatu oníṣẹ́ ọnà pẹ̀lú ìṣó àti òwú