BBC 100 Women 2019: Wo ọmọ Nàíjíríà kan tó wà nínú wọn

Images of many of the BBC's 100 Women 2019

Ileesẹ BBC ti si asọ loju awọn obinrin ọgọrun to lami laaka juls yika agbaye fun ọdun 2019.

Lọdun yii, ibeere tawọn obinrin ọgọrun naa n beere ni pe: Bawo ni ọjọ ọla yoo ti ri to ba jẹ pe awọn obinrin lo dari rẹ?

Bẹrẹ lati ori Ayaworan ile to n gbero lati tun orilẹede Syria kọ, titi de ori alakoso isẹ ajọ NASA to n mojuto ọkọ ofurufu to n lọ si inu ofurufu Mars, ọpọ awọn obinrin to wa ni akọsilẹ ọgọrun naa ni wọn ti pegede ninu isẹ ti wọn yan laayo, ti wọn yoo si sọ asọtẹlẹ fun wa nipa bi ayeyoo se ri ti yoo ba fi di ọdun 2030.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn yoku, bii 'Iwin' oloselu to maa n sori kunkun si awọn ẹgbẹ imulẹ taa mọ si mafia, to fi de ori awọn agbabọọlu ti wọn n dẹyẹ si tori pe wọn jẹ obinrin, gbogbo wọn lo n lo iriri wọn lati la ọnafun awọn to n bọ lẹyin.

Awọn orukọ obinrin ọgọrun fọdun 2019 la to si isalẹ yii gẹgẹ bi orukọ wọn ti lọ, isẹ ti wọn yan laayo, orilẹede wọn ati itan igbe aye wọn.

Salwa Eid Naser - Elere idaraya to jẹ ọmọ Naijiria ati Bahrain

Salwa Eid Naser lo sare julọ nilu Doha, to si jẹ asaaju laarin awọn obinrin to ti n kopa ninu idije ere sisa oni irinwo mita, lati ọgbọn ọdun sẹyin.

Ọmọbibi ipinlẹ Anambra lorilẹede Naijiria ni, amọ to rekọja si orilẹede Bahrain lọmọ ọdun mẹrinla, ko lee ri anfaani lati tẹsiwaju ninu ere sisa to yan laayo, to si n soju arin gbungbun agbaye bayii.

Judity Bakira - Agbẹ lati Uganda

Inu oko kan lorilẹede Uganda ni wọn ti wo Judity Bakira dagba, to si di ẹni akọkọ laarin awọn akẹẹgbẹ rẹ ti yoo janfaani ẹkọ ọfẹ lọ sile ẹkọ awọn obinrin to gbajugbaja, to si ti ibẹ ls silẹ UK lati gba oye imọ ijinlẹ keji, to si tun n sisẹ nibẹ.

Nigba ti isẹ naa ko ba lara mu, lo ba ko awọn owo to ri fi pamọ pada si Uganda, to si n se ọgbin eso ati agbo.

Lati igba to ti gba ami ẹyẹ nidi eto ọgbin, lo ti n lo anfaani naa lati fi pe akiyesi awọn obinrin si ẹtọ wọn, to fi mọ aini anfaani si rira ilẹ, ailọ sile ẹkọ ati iwa ipa ninu ile sawọn obinrin.

Lucinda Evans - Ajafẹtọ ẹni lati South Africa

Nibayii ti orilẹede South Africa n koju iwa ipaniyan ati ifipabanilopọ to le pupọ, Lucinda ti dide gẹgẹ bii agbẹnusọ fun awọn obinrin. Oun si lo siwaju iwọde kan to waye yika orilẹede naa, to ko ẹgbẹlẹgbẹ awọn obinrin kaakiri igboro ilu Cape Town, to si n pe ijọba orilẹede naa nija lati se amusẹ ofin to jẹ isẹlẹ yii.

Lucinda lo sedasilẹ eto kan to pe ni ẹ wo awọn obinrin wa san, eyi tii se ẹgbẹ ti ko wa lati ko ere jọ, , amọ to n gba awọn obinrin ni imọran, maa se idanilẹkọ fun wọn, to si tun maa n lọ yika igberiko lati se awari awọn obinrin ti wọn ba ji gbe pẹlu ipese ilegbe fun awọn obinrin to ba sa asala fun iwa ipa ninu ile.

Asmaa James - Ajafẹtọ ẹni ati Akọroyin ni Sierra Leone

Asmaa lo jẹ agbẹnusọ fun awọn obinrin lorilẹede Sierra Leone lati ipasẹ isẹ akọroyin ati osisẹ amayedẹrun to n se.

Lẹyin to gbọ pe wọn ba ọmọ ọdun marun lopọ ni tipa, lo ba lo ileesẹ iroyin rẹ lati se ifilọlẹ eto ipolongo 'Black Tuesday' eyi to n se iwuri fun awọn obinrin lati wọ asọ dudu lawọn ọjọ Isẹgun to kẹyin osu, lọna ati fẹhonu han lori iwa ifipabanilopọ ati ilokulo ọmọbinrin ti ọjọ ori wọn ko tii to ọdun mejila.

Igbesẹ naa si lo mu ki ileesẹ aarẹ orilẹede Sierra Leone gbe igbesẹ lati se amusẹ ati atunse ofin to n gbogun ti iwa ifipabanilopọ.

Precious Adams - Onijo nilẹ Amẹrika

Precious Adams, lati Ọmọ ọdun mẹjọ, lo ti n lo ọpọ akoko lati maa jo kiri yara igbalejo ti iya rẹ fi ọwọ si fun lati maa lo fun idanilẹkọ. Nigba ti yoo fi di ọmọ ọdun mẹrindinlogun, o ti lọ sawọn ileẹkọ nipa ijo jijo mẹta to dantọ julọ lagbaye.

O gba ami ẹyẹ, to si n fọnrere pe ki awọn onijo maa wọ sokoto fẹlẹfẹlẹ to fun mọra, to si ba awọ ara ẹni to n jo mu.

Parveena Ahanger - Ajafẹtọ ẹni nipa agbegbe Kashmir ti orilẹede India n dari

Parveena ni wọn n pe ni obinrin alagbara lagbegbe Kashimir, Kashimir Iron lady, ti ọmọkunrin rẹ si poora lọdun 1990 nigba ti wahala naa de oju ẹ.

Eyi lo mu ki Parveena se agbekalẹ ẹgbẹ awọn obi ọmọ to poora , to si ni oun ko tii sọ ireti nu pe oun ko ni ri ọmọ oun mọ, nibayii ti yoo pe ọgbọn ọdun ti ọmọ rẹ naa poora.

Piera Aiello - Oloselu ni Italy

Piera ni wọn n pe ni 'Iwin' oloselu to n poora, ẹni to du ipo oselu pklu iboju loju rẹ, nitori idunkooko lati ọdọ awọn ọgbẹ imulẹ mafia.

Lọdun to kọja, nigba to bori ibo naa gẹgẹ bii oludije to n tako ẹgbẹ awo, lo wa si oju rẹ sita fun araye lati ri.

O lo iriri rẹ gẹgẹ bii ọmọ ọdun mẹrinla ti wọn fi tipa mu lati fẹ ọmọ ọga kan ninu ẹgbẹ awo mafia , lati fi maa beere fun ẹtọ awọn eeyan to n se ofofo fun awọn ọlọpa ati mọlẹbi wọn.