Aisha Buhari: Ẹ wo ohun tó mú u yàtọ̀ sí àwọn ìyàwo ààrẹ tó ti kọjá

Aisha Buhari Image copyright @aishambuhari
Àkọlé àwòrán Aisha Buhari: Ẹ wo ohun tó mú Aisha Buhari yàtọ̀ sí àwọn ìyàwo ààrẹ tó ti kọjá

Aisha jẹ aya aarẹ Muhammadu Buhari to da yatọ lara awọn iyawo aarẹ to ti ṣejọba sẹyin ni Naijiria.

Ọpọ awọn aya aarẹ Naijiria to ti kọja ni wọn ti gbe nkan nla ṣe loriṣiriṣi.

Diẹ lara awọn aya aarẹ ti ọpọ ti sọrọ nipa wọn sẹyin lori ìṣe wọn ni: Maryam Babangida, Maryam Abacha, Stella Obasanjo, àti Patience Jonathan.

Diẹ lara awọn iṣẹ ti awọn aya aarẹ ti gbe ṣe lọọfiisi wọn sẹyin ni Better Life for rural women ti Maryam Babangida ṣe, Family Support ti Maryam Abacha ṣe.

Women and Youth Empowerment Foundation ti aya Yaradua ṣe, Child Care Trust ti Stella Obasanjo ṣe ṣaaju iku rẹ ati Women for change initiative ti Patience Jonathan ṣe.

Image copyright Patience
Àkọlé àwòrán Ọpọ awọn aya aarẹ to ti kọja kii da fi ọkọ wọn silẹ ninu iṣejọba

Ẹ wo awọn ohun diẹ eleyi to mu Aisha Buhari yatọ sawọn iyawo aarẹ ẹgbẹ rẹ tẹlẹri.

1. Sisọrọ nita tako Iṣejọba ọkọ rẹ

O jẹ ohun aridaju pe ko si obinrin kankan lara awọn iyawo aarẹ orilẹ-ede yii to tii sọrọ alufaṣa nipa iṣejọba ọkọ wọn ni gbangba Mo sọ̀rọ̀ tako ọkọ mi torí òtítọ́ - aya Bùhárí.

Gbogbo awọn iyawo aarẹ to ti jẹ tẹlẹ lo maa n sọrọ ijọba ọkọ wọn nire, yala o ṣe daradara tabi ni ida keji Aisha Buhari sàtìlẹyìn fáwọn ọ̀dọ́ tó fọnmú lórí ìyànsípò àwọn alátakò sínú ìjọba APC.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Aisha Buhari: Ẹ wo ohun tó mú Aisha Buhari yàtọ̀ sí àwọn ìyàwo ààrẹ tó ti kọjá

Ninu ifọrọwerọ kan lọdun 2016 ni Aisha ti kọkọ bu ẹnu atẹ lu ijọba ọkọ rẹ Ìgbà Marún-un ti Aisha Buhari ti tako ìjọba Buhari.

Ninu ifọrọwerọ naa lo ti sọ pe oun ko ni ṣatilẹyin fun Buhari ninu idibo sipo aarẹ lọdun 2019, nitori pe ko ṣe daadaa fawọn to ṣiṣẹ fun un lati de ipo aarẹ ni saa kini rẹ, ti ọrọ ọhun si da ọpọ rogbodiyan silẹ

2. Ko lẹnu ọrọ ninu ijọba ọkọ rẹ bii tawọn to ku

Ọpọ awọn ọmọ Naijiria lo lero pe Aisha ko lẹnu ninu iṣejọba ọkọ rẹ ati pe aarẹ Buhari ko faaye gbaa to ninu iṣejọba rẹ Aisha Buhari ké gbàjare pé ètò ìjọba Buhari kò ṣànfàní f'óbìrin.

Bi ẹ ko ba gbagbe iyawo aarẹ ana, Patience Jonathan, niṣe lo dabi pe ko si ibi ti ko ki n tẹle ọkọ rẹ lọ sugbọn ti Aisha ko ri bẹẹ.

Nigba ti aarẹ Buhari ṣaisan ranpẹ leyi to mu ko lo ọpọlọpọ ọjọ ni ilu London, wọn ni Aisha ko kọkọ tẹle aarẹ Buhari ṣaaju nigba ti aisan naa bẹrẹ.

Eyi yatọ patapata si ti aya aarẹ Yaradua nibiti aya aarẹ Umaru Musa Yaradua ṣe awọn nkan kan ti aye tori wọn pariwo lasiko ti ọkọ rẹ n gba itọju ni saudi Arabia fun igba pipẹ.

3. Ọọfiisi aya aarẹ ninu ofin Naijiria?

Ninu iwe ofin Naijiria, ko si iṣẹ alakalẹ lọtọ fun iyawo aarẹ Naijiria pe ko fi da gba ọọfiisi ara rẹ tẹlẹ.

Ṣugbọn awọn aarẹ to ti kọja kan ni wọn bẹrẹ igbesẹ lori ọọfiisi aya aarẹ Naijiria diẹdiẹ.

Ọọfiisi yii faaye gba ki aya aarẹ funrarẹ ni awọn anfaani kọọkan; bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ to n ri si eto inawo Naijiria kii ya owo sọtọ ninu iṣuna Naijiria fun aya aarẹ lati na ṣugbọn iwadii fihan pe ileeṣẹ to n ri si ọrọ awọn obinrin ni Naijiria maa n firu owo yii silẹ lara eyi to gba ninu eto iṣuna Naijiria.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn aya aarẹ miran gan an ni ara ilu gab pe wọn ni agbara to pọ ninu iṣejọba ọkọ wọn

Lọdun 2014 ni iroyin ni aarẹ Buhari kede pe oun ko ni faaye gba ọọfiisi iyawo rẹ bii obinrin akọkọ lorilẹ-ede ti oun ba wọle sipo ni eyi to kọkọ ri bẹẹ Ta ni yóò borí láàrin Aisha Buhari àti ọkọ rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ ‘First Lady’?.

Ninu iṣejọba aarẹ Buhari lẹẹkeji yii, ni nkan ti yipada ti Aisha naa si ti di ipo naa mu pẹlu ọọfiisi atawọn eeyan to n ṣiṣẹ fun un bayii Funke Adesiyan, òṣèré Yollywood tó di olùrànlọ́wọ́ aya ààrẹ, Aisha Buhari .

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionNigeria Independence Day: Wo ìlérí tí àwọn ènìyàn ṣe

4. Ede-aiyede Aisha pẹlu awọn mọlẹbi ọkọ rẹ

O ṣoro lati sọ boya awọn iyawo aarẹ ana maa n ba awọn mọlẹbi ọkọ wọn ja abi bẹẹkọ nitori ko jade sita.

Ṣugbọn ni ti Aisha, o han kedere pe ohùn rẹ ko ṣokan pẹlu awọn ẹbi ọkọ rẹ "Ọmọ Daura ti tàpá sí òfin ààbò Nàíjíríà, ó sì yẹ kí Buhari le è to ilé rẹ̀" ..

Laipẹ yii ni fidio kan jade lori ẹrọ ayelujara, nibi ti Aisha ti n binu, ti wọn ni o n sọrọ alufanṣa si Fatima Mamman Daura to jẹ mọlebi ọkọ rẹ Taló ya fídíò ibi tí Aisha Buhari ti ń bínú ní Aso Rock?

Bo tilẹ jẹ pe iyawo aarẹ ni fidio naa ti pe, o ti tọrọ aforiji lọwọ awọn ọmọ Naijiria lori fidio ọhun Ọmọ Nàìjíríà, ẹ forijìn mí! Aisha Buhari tọrọ ìdáríjì lórí fídìo tó jáde.

Eyi lo mu awọn eeyan kan gba pe Aisha ko ri oju Buhari ọkọ rẹ nilẹ bo ṣe wuu.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionPainter: Samuel ni ìdàgbàsókè Nàìjíríà ló jẹ òun lógún!

5. Ọdọmọde laaye ara rẹ ni Aisha:

Aisha Buhari ni aya aarẹ orilẹ-ede Naijiria to kere lọjọ ori julọ yatọ si Maryam Babangida to jẹ ọmọ ọdun mẹtadinlogoji nigba naa.

Yatọ si pe Aisha kere lọjọ ori, imura rẹ ati ihuwasi rẹ fi ti awọn obinrin ti ko tii darugbo nilẹ Adulawọ han paapaa bo ṣe n sọrọ lori ayelujara.

Imura Aisha paapaa nilẹ okeere n jẹ ki awọn ọdọbinrin gba tiẹ pupọ nitori pe wọn gba pe Aisha gbọ faari pupọ.

Image copyright @Aisha
Àkọlé àwòrán Imura Aisha yaa sọtọ

6. Aisha kọ lati fi ọrọ sabe ahọn sọ pe aarin oun ati Buhari ọkọ rẹ ko gun to lasiko kan:

Bi awọn kan ṣe n gboriyin fun Aisha pe o sọrọ sita to dẹ tun huwa to fihan pe aarin oun ati ọkọ rẹ ko gun to naa ni awọn mii ni ko yẹ ko ṣe bẹẹ.

Ko sẹni to le sọ ni pato nkan to n ṣẹlẹ ni Aso Rock laarin lọkọ laya yii ṣugbọn idahun Aisha si ibeere pe ọkọ rẹ n gbero ati gbe iyawo lee fidi wahala inu ile mulẹ Èmi kò sí nílé, ọkọ́ mi ló leè sọ bóyá lóòtọ́ọ́ ló fẹ́ gbéyàwó àbí bẹ́ẹ̀ kọ́ - Aisha fèsì.

Laipẹ yii ni iroyin gba ori aye lujara kan pe aarẹ Buhari fẹ gbe iyawo tuntun Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìròyìn òfegè ni pé Buhari fẹ fẹ́ Sadiya, síbẹ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ń ṣètò ìyàwò náà lórí ayélujára .

Eyi ni ọpọ gba pe Ooṣa jẹ n pe meji obinrin ko kuku denu ri ati pe Ta ni Sadiya Umar Farouq tí ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ ń gbé pé òun ló fẹ́ dí ìyàwó tuntun Buhari?

Ojọ igbeyawo ofege yii ni awọn eniyan Naijiria ṣe e bo ṣe wu wọn lori ayelujara.

Ni eyi ti ọpọ tun lọ kirun ni Mọṣalaṣi lati foju lounjẹ Èrò yapa ní mọ́ṣáláṣí Jimọ̀h láti wá fójú lóúnjẹ lórí ìgbéyàwó òfegè Buhari.

Image copyright others
Àkọlé àwòrán Se Buhari fẹ fe iyawo le Aisha nitootọ?

Bi ẹ ko ba gbagbe, ọpọ igba ni iroyin n gbee pe aarẹ Goodluck Jonathan n fẹ Diezani Allison Maduekwe to jẹ minista fun ọrọ epo rọbi nigba naa ṣugbọn ti Patience ko figba kankan sọrọ lori rẹ ni eyi to tun yatọ si Aisha.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAdebisi Olabode: Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ti fòfin de oyè Ìyá àti Babalọja