ChildMarriage: Ìmọ̀ òdì ẹsin Islam ló ń mú kí àwọn èèyàn bímọ bẹẹrẹ ni Niger– Issoufou

Aarẹ orilẹ-ede Niger, Mahamadou Issoufou Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ìmọ̀ òdì ẹsin Islam ló ń mú kí àwọn èèyàn bímọ bẹrẹ ni Niger - Ààrẹ Mahamadou Issoufou

Aarẹ orilẹ-ede Niger, Mahamadou Issoufou ti sọ pe, bi awọn ọmọ orilẹ-ede ọhun ṣe n bimọ bẹẹrẹ jẹ imọ odi ti wọn ni nipa ẹsin Islam.

Ninu ifọrọwerọ kan ti aarẹ ọhun ṣe pẹlu akọroyin iwe iroyin UK Guardian, o ni bi awọn eeyan orilẹ-ede naa ṣe n pọ si i n mu adinku ba ilọsiwaju orilẹ-ede ọhun.

Ida mejidinlọgọrun un awọn ọmọ orilẹ-ede Niger lo jẹ Musulumi.

Oye awọn eeyan orilẹ-ede naa si ti di miliọnu mejilelogun, eyi to jẹ afikun lati miliọnu mẹjọ to wa lọdun 1990.

Aarẹ Issoufou ni awọn eeyan orilẹ-ede Niger n le si i ni ida mẹrin ninu ọgọrun un lọdọọdun.

O ni o ṣeeṣe ki ero orilẹ-ede ọhun di ilọpo meji ko to di ọdun 2050.

O ṣalaye pe, orilẹ-ede naa lee de ipo keji ninu awọn orilẹ-ede to pọ ju nilẹ Afirika lẹyin Naijiria, leyi ti ipa ọrọ aje orillẹ-ede ọhun ko le ka.

Issoufou ni Kurani kọ awọn obi lati bi oye ọmọ ti wọn le tọ nikan, kii ṣe ki wọn maa bimọ bẹrẹ.

Aarẹ ọhun ni, ki ẹsin Musulumi to de, awọn obinrin n lọ sile ọkọ lọmọ ọdun mejidinlogun, sugbọn ni bayii, awọn obinrin ti n lọ ile ọkọ lọmọ ọdun mejila si mẹtala.

Ni eyit ti ko yẹ ko ri bẹẹ ati pe ko ṣẹyin aṣitumọ iwe mimọ Kurani ti wọn ko tumọ daadaa ni Aarẹ Mahamadou gba pe o n ṣokunfa eyi ni Niger.

O ni Kurani sọrọ nipa itọju awọn ọmọ ti eeyan ba bi ki ẹni naa si tọ wọn daadaa, kii ṣe pe ki o kan maa bimọ da silẹ lasan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionPainter: Samuel ni ìdàgbàsókè Nàìjíríà ló jẹ òun lógún!