Àdó olóró pa èèyàn 62 tó ń gbàdúrà ní Mọ́ṣáláṣí Afghanistan

Ọdọkunrin to n gba itọju lẹyin akọlu naa Image copyright EPA
Àkọlé àwòrán Ọdọkunrin to n gba itọju lẹyin ikọlu naa lagbegbe Nangarhar

Ko din ni eeyan mejilelọgọta to ti dero ọrun, ti ọpọ si farapa lẹyin ti ado oloro kan dún ni Mọṣalaṣi ti awọn eeyan ti n gbadura lorilẹ-ede Afganistan.

Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn sọ pe ibu gbamu ado oloro ọhun mi Mọṣalaṣi naa, to si ba orule rẹ jẹ.

Ikọlu yii lo waye lẹyin ọjọ kan ti ajọ iṣokan orilẹ-ede agbaye, UN sọ pe, bi wọn ṣe n pa awọn ara ilu ni orilẹ-ede Afganistan ti n kọja oju ẹ.

UN ni, awọn ara ilu to le lẹgbẹrun un kan ni wọn ti ṣeku pa laarin oṣu keje si oṣu kẹsan an ọdun 2019 nikan, eyi to jẹ akọsilẹ to ga ju lati ọdun mẹwaa sẹyin.

Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán ọpọ ẹmi sọnu lasiko irun Jimoh ni Afghanistan

Iwadii ti BBC ṣe fihan pe, ida aadọta ninu awon awọn eeyan to ba iṣekupani naa lọ jẹ awọn ara ilu ti ko mọwọmẹsẹ.

Oluṣakoso agbegbe ti ado oloro ọhun ti burẹkẹ, Attaullah Khogyani, sọ fun BBC pe, eeyan mejilelọgọta lọ ba iṣẹlẹ ọhun lọ, ti mẹrindinlogoji si farapa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionPainter: Samuel ni ìdàgbàsókè Nàìjíríà ló jẹ òun lógún!

Iwadii ṣi n lọ lọwọ lati mọ ẹgbẹ to ṣe ikọlu naa, sugbọn ẹgbẹ alakata kiti Islam ti wọn pe ni agbesumọmi Taliban ni oun ko lọwọ ninu iṣelẹ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAdebisi Olabode: Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ti fòfin de oyè Ìyá àti Babalọja