Ẹ ka díẹ̀ lára àwọn ìṣẹlẹ̀ ayọ̀ lágbo òṣèré tíátà Yollywood láàrin ọ̀sẹ̀ yìí

Funke Akindele, Ibrahim ati Wumi Torila Image copyright @Others
Àkọlé àwòrán Bi awọn kan ṣe n ṣe ọjọ ibi, awọn mii bimọ tuntun, awọn miran si goke agba sii lẹnu iṣe pẹlu awọn oloṣelu

Ọpọlọpọ nkan lo ṣẹlẹ laarin ọsẹ yii lagbo oṣere tiata Yollywood.

Díẹ̀ rèé lára àwọn ohun ayọ tọ ṣẹlẹ̀ lágbo òṣèré tíátà láàrin ọ̀sẹ̀ yìí

Bi awọn kan ṣe n ṣajọyọ pe oju wọn ri ọdun ti obi wọn ko pa ọdun 2019 jẹ, ni awọn mii bimọ tuntun, ti awọn miran si goke agba sii lẹnu iṣe pẹlu awọn oloṣelu.

Wumi Toriola di iya ikoko:

Oṣere sinima to ṣẹṣẹ n gbori soke ni Wumi Toriola, sugbọn tọmọde tagba lo mọ ọ Àwọn ojú oge Yollywood t'ọ́jà wọ́n ṣì ń tà wàràwàrà .

Ọdun 2018 ni Wumi ṣe igbeyawo pẹlu ọkọ rẹ to n gbe nilẹ okeere.

Lọsẹ yii lo di abiyamọ tuntun lagbo oṣere Yoruba, lẹyin ti Ọlọrun fun idile rẹ ni ọmọ okunrin lantilanti.

Funke Adesiyan

Ọjọ kẹtadinlogun oṣu yii nile iṣẹ iyawo aarẹ orilẹ-ede Naijiria, Aisha Buhari kede oṣere tiata yii gẹgẹ bi ọkan lara awọn oluranlọwọ pataki rẹ Funke Adesiyan, òṣèré Yollywood tó di olùrànlọ́wọ́ aya ààrẹ, Aisha Buhari.

Funke jẹ ọkan gboogi lara aṣere sinima Yoruba.

O si wa lara awọn oṣere ti Eleduwa fun lẹbun ere ṣiṣe lagbo awọn oṣere.

Bi iyawo aarẹ ṣe yan Funke sipo jẹ iyalẹnu fun ọpọ eeyan, sugbọn o ti n ba iyawo aarẹ ṣiṣẹ tẹlẹ ko to di akoko yii.

Jumoke Odetola

Image copyright @TernopilInkling
Àkọlé àwòrán Ilu Eko ni wọn bi Jumoke si lọdun 1983

Lọseyi ni gbajugbaja oṣere tiata Yoruba yii ti ọpọ n pe ni "Higi-haga" ṣe ọjọ ibi rẹ.

Ilu Eko ni wọn bi Jumoke si lọdun 1983.

Ọjọru ọsẹ yii, to jẹ ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹwaa, ọdun 2019 ni Jumoke pe eni ọdun mẹrindinlogoji laye.

Funke Akindele

O ṣeeṣe ki Funke gunle irinajo pọn lọ si ile Dubai laipẹ yii o.

Lọjọbọ ọsẹ yii ni Funke gbe ọrọ kan lede loju opo Intsgram rẹ, nibi to ti n beere lọwọ awọn ololufẹ rẹ erongba wọn lori isinmi lorilẹ-ede United Arab Emirates.

O ni "Mo ro pe mo nilo lati lọ sinmi! Ṣe ki n lọ si Dubai pẹlu awọn temi ni?

Nibẹ naa ni ọpọ awọn ololufẹ rẹ ti n fesi pe, awọn ṣetan lati tẹle lọ irinajo ọhun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMama Rainbow: Toyin Adegbola àti Razak Olayiwola ní ìyá rere àti àwòkọ́ṣe gidi ní

Mama Rainbow

Idowu Philps ti ọpọ eeyan mọ si Mama Rainbow, Iya Oṣumare naa ṣe ọjọ ibi rẹ ninu ọsẹ yii.

Ọpọlọpọ awọn akẹgbẹ Mama Rainbow ninu iṣẹ tiata ni wọn yẹ ẹ si nibi ayẹyẹ ọjọ ibi ọhun, nigba to n ṣe ayẹyẹ ẹni odun mẹtadinlọgọrin loke eepẹ.

Tijo tayọ ni Mama fi n dupẹ lọwọ Ọlọrun to da ẹmi rẹ si, ati awọn to yọju sibi ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ ọhun pe aanu Oluwa ni oun ri gbà!

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionPainter: Samuel ni ìdàgbàsókè Nàìjíríà ló jẹ òun lógún!

Ibrahim Chatta

Lara awọn ti Ọlọrun gba fun ninu iṣe tiata Yoruba ni Ibrahim Chatta jẹ

Laarin oṣẹ yii ni Chatta le ọdun kan si i nilẹ alaye.

Image copyright @paj1official
Àkọlé àwòrán Lara awọn ti Ọlọrun gba fun ninu iṣe taiata ni Ibrahim Chatta

Ọpọ ninu akẹgbẹ rẹ ninu iṣe tiata ni wọn si ba Chatta ṣe ajọyọ ọjọ ibi ọhun.

Bi awọn mọlẹbi re ṣe fi ẹbun ranṣẹ si i naa ni awọn ololufẹ rẹ n ki i ni mẹsan an-mẹwaa lori ẹrọ ayelujara.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionNigeria Independence Day: Wo ìlérí tí àwọn ènìyàn ṣe