Ètò àbò, epo bẹntiró àti ọrọ̀ ajé ló gbé Buhari lọ sí Russia

Muhammadu Buhari Image copyright BAYO OMOBORIOWO
Àkọlé àwòrán Buhari yoo ti ṣe ipade pẹlu aarẹ ilẹ Russia, Vladimair Putin, lori ajọṣepọ to wa laarin orilẹ-ede mejeji

Olubadamọran pataki fun aarẹ Muhammadu Buhari lori iroyin, Garba Shehu ti sọ pe eto abo, epo bẹntiro ati ọrọ aje lo gbe aarẹ lọ si orilẹ-ede Russia loni.

Shehu lo sọ ọrọ yii ninu atẹjade kan to fi lede loju opo Twitter rẹ.

O ni ijiroro ọhun ti yoo waye fun ọjọ mẹta gbako yoo bẹrẹ lati ọjọ kẹtalelogun si ọjọ karundinlọgbọn oṣu yii.

Irinajo naa ti aarẹ gunle da lori bi orilẹ-ede Naijiria ṣe le ṣamulo anfani idagbasoke orilẹ-ede Russia, lori eto ọrọ aje, idokoowo, eto abo, eto ọgbin, ati bẹbẹ lọ.

Nibi ijiroro naa ni aarẹ Buhari yoo ti ṣe ipade pẹlu aarẹ ilẹ Russia, Vladimair Putin, lọna lati mu ajọṣepọ to wa laarin orilẹ-ede mejeji mokun sii.

Ijijroro ọhun ni awọn olori ilẹ Afirika miran yoo peju si, nibi ti wọn yoo ti ṣe ipade lori bi Russia ṣe le ṣeranwọ fun ilọsiwaju ile adulawọ lapapọ

Bakan naa ni awọn agba ọjẹ oniṣowo nilẹ Afirika yoo peju sibi ipade ọhun, nibi ti wọn yoo ti forikori lọna lati mu ki idoko-owo orilẹ-ede Rusia ati ilẹ adulawọ le tẹsiwaju.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIsheri Flood: Àwọn olùgbé Isheri ń sanwó fún ọkọ̀ ojú omi láti rìn ní àdúgbò