Russia in Africa: Ṣé òun ni alágbára ńlá ní Áfíríkà báyìí?

Aarẹ Putin ati Basir Image copyright Getty Images

Orilẹede Russia lo n gbalejo ipade apapọ awọn asaaju orilẹ-ede Áfíríkà lọsẹ yii, eyi to n fihan pe agbega ti n ba ipa to n ko nilẹ Áfíríkà.

Lootọ ni orilẹede Soviet Union laye igbakan ni ojuse to fidi mulẹ ni ilẹ Afirika tẹlẹ amọ ipa rẹ ni ẹka ọrọ aje ati oselu ti dinku lẹyin ogun abẹle keji.

Aarẹ Putin salaye pe sise amugbooro okun ajọsepọ laarin awọn orilẹede Afirika jẹ ọkan lara awọn ilana ilẹ okeere to jẹ wọn logun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Eyi si lo mu ki ẹka ileesẹ BBC to maa n wadi ọfintoto nipa iroyin kan, ti wọn n pe ni BBC Reality Check, fi n beere pe bawo ni ojuse orilẹede Russia ni ilẹ Afirika ti se pataki si lọwọlọwọ bayii?

Ki ni erongba orilẹede Russia?

O ti foju han gbangba pe Russia wa digbi, to si fẹsẹ rinlẹ lati mu ki okun ajọsepọ rẹ lati aye Soviet Union nilẹ Afirika tubọ le si.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu ileesẹ akoroyinjọ ilẹ Russia, TASS saaju ipade apero to waye lọsẹ yii, aarẹ Putin ni "Ibasepọ laarin Russia ati awọn orilẹede Afirika naa wa loke tente, to si tun sọrọ nipa fifun wọn ni awọn anfaani yii:

  • Atilẹyin lẹka ọrọ oselu ati ibasepọ laarin orilẹede
  • Eto aabo ati iranwọ lori aabo
  • Iranwọ lẹka ọrọ aje
  • Imọran nipa akoso aisan
  • Ipese eto iranwọ fun ọmọniyan
  • Idanilẹkọ fun isẹ ọwọ ati eto ẹkọ
Image copyright Getty Images

Orilẹede Russia ti n se amugbooro ẹka agbara rẹ nidi eto iselu lẹkun Afirika, tawọn olori orilẹede lẹkun naa mejila si n se abẹwo si Russia lati ọdun 2015, mẹfa ninu wọn si tun ls si Russia ni 2018 nikan.

Ibasepọ Russia pẹlu awọn orilẹede Afirika lẹka ologun

Orilẹede Russia jẹ alabasepọ aabo fawọn orilẹede kan ni Afirika, to si jẹ ogbontagi laarin awọn to n pese ohun ija oloro fun wọn, sugbọn taa ba wo yika agbaye, ilẹ Aifika kọ lo tobi ju ti wọn n ta awọn ohun ijagun rẹ si, ẹkun Asia ni.

Amọ sa, ajọsepọ rẹ lkka aabo n fẹju si lati ọdun 2014, to si fọwọsi iwe adehun ibasepọ ologun pẹlu awọn orilẹede mọkandinlogun nilẹ Afrika.

Lilo awọn ọmọ ogun labẹnu

Ajọsepọ Russia lẹka ologun ati aabo kọja kiko ohun ijagun lọ silẹ okeere, nigba miran, o tun maa n lo awọn ikọ ologun aladani labẹnu.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn ọmọ ogun aladani to n pese aabo lorilẹede Central African Republic

Yatọ si orilẹede Central Africa Republic ti ifarahan Russia ti fẹsẹ mulẹ, bakan naa la tun gbọ pe lorilẹede Sudan ati Libya atawọn orilẹede miran, ileesẹ ologun aladani kan, Wagner, ti wọn lo ni ajọsepọ to gunmọ pẹlu Russia, wa nibẹ.

Ohun alumọọni ilẹ

Russia ni awọn eto afanilojumọra lorisirisi lẹka ọrọ aje eyi ti yoo mu ko fidi kalẹ ni Afirika bi ko tilẹ ni awọn eroja kan lọpọ fun awọn ileesẹ nlanla rẹ.

Bakan naa ni Russia ni iriri pupọ lẹka ohun amusagbara eyi to lee lee fi fa oju awọn orilẹede to ni ohun alumọọni lọpọ loju mọra.

Image copyright Petra Diamonds
Àkọlé àwòrán Iwakusa eroja okuta Diamond jẹ ara ohun to fa orilẹede Russia loju mọra

Koda, awọn ileesẹ kan to jẹ tilẹ Russia lo ti n wa kusa lorilẹede Guinea, ti wọn si tun n wa okuta olowo iyebiye dayamọndi ni orilẹede Angola, to si tun ti gba asẹ lati maa pese afẹfẹ gaasi lorilẹede Mozambique.

Tun wẹ, ileesẹ aladani nla to wa fun ohun amusagbara lati Russia, Lukoil, la tun gbọ pe o n se isẹ lorilẹede Cameroon, Ghana ati Naijiria, to si tun n lakaka lati tẹdo si orilẹede Congo.

Russia tun n pese iranwọ nidi imọ ẹrọ igbalode nidi ohun ijagun oloro fun ọpọ awọn orilẹede ni ilẹ Afirika, to fi mọ sise agbekalẹ ibudo ipese ohun eelo ijagun oloro lorilẹede Egypt lọdun to n bọ, eyi ti yoo na wọn to owoya biliọnu mẹẹdọgbọn dọla.

Ẹka ileesẹ BBC, ti wọn n pe ni BBC Reality Check lo n tanna wadi otitọ to ba wa nidi iroyin kan lati mọ boya ootọ ni abi irọ.