Ajax vs Chelsea: VAR ṣ'ègbè lẹ́yìn Chelsea f'ogun ẹ̀yín ja Ajax mọ́lé

Michy Batshuayi lẹyinn to sọ bọọlu sinu awọn Ajax Image copyright @Chelsea4Pidgin
Àkọlé àwòrán VAR ṣègbè lẹ́yìn Chelsea fogun ẹ̀yín ja Ajax mọ́lé

Ifẹsẹwọnsẹ UEFA Champions League laarin ikọ Ajax ati Chelsea to waye lalẹ oni le koko bi oju ẹja, ṣugbọn ikọ Chelsea fẹ Ajax danu nile wọn.

Ni igba ti idije naa wọ iṣeju mẹtalelọgbọn ni Quincy Promes sọ ayo kan wọle fun ikọ Ajax, ṣugbọn lẹyin isẹju die si ti wọn wo oju ẹrọ ni VAR ni rẹfiri wọgi le goolu ọhun.

Ọ̀mì ni ikọ memeji gba ni ipari abala akọkọ ifẹsẹwọnsẹ ọhun.

Gbogbo akitiyan Quincy Promes ninu abala keji ifẹsẹwọnsẹ naa lati sọ bọọlu sinu awọn ikọ Chelsea lo ja si pabo, ko to di pe wọn parọ rẹ.

Ṣugbọn nigba ti o ku iṣeju mẹrin ki ifẹsẹwọnsẹ ọhun pari ni Michy Batshuayi fi ibinu sọ ami ayo kan sinu awọn ikọ Ajax.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ agbábọ́ọ̀lù Chelsea ya àgbàdo hà sí ikọ́ Ajax lẹnu lẹ́yìn tí wọ́n lù wọ́n mòlé

Eyi mu ki akọnimọgba ikọ Ajax Erik ten Hag, parọ awọn ọmọ rẹ meji ni wara wara, ṣugbọn ẹpa ko boro mọ.

Bo tilẹ jẹ pe akọnimọgba ikọ Chelsea naa parọ lara awọn ikilọ rẹ, ti wọn gbiyanju lati sọ ayo miiran sinu awọn.

Lẹyin iṣẹju mẹrindinlọgọrun un ni ifẹsẹwọnsẹ naa pari ni ikọ Chelsea fẹ Ajax danu bi abẹbẹ pẹlu ami ayo kan si odo.