Catholism: Ìdìbò náà ló tako àṣà kí àwọn àlùfáà ìjọ máṣe fẹ́ ìyàwó

Awọn alufa ijọ katoliki ni Naijiria

Oríṣun àwòrán, @BiafraHouse

Awọn Bisọọbu Ijọ Aguda ti dibo lati gba awọn baale ile laaye lati jẹ Alufa ni agbeegbe Amazon, eleyii ti yoo tako ipilẹ ijọ naa to ni pe awọn alufaa ki i fẹ iyawo.

Awọn Bisọọbu naa di ibo yii lasiko ipade apapọ gbogbo-gboo Synod, nibi ti awọn bisọọbu to le ni ọgọrun ti pejọ ni Vatican ni agbeegbe Amazon, nibi ti awọn alufaa ti sọwọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn ọmọ ijọ Aguda to bu ẹnu atẹ lu igbesẹ naa ni ko yẹ ki wọn gba awọn baale ile laaye lati jẹ alufaa nitori yoo ba ododo ati iwa mimọ ti o rọ mọ isẹ alufaa ninu ijọ naa.

Amọ awọn ti wọn gboriyin fun igbesẹ naa ni awọn baale ile ti awọn eniyan mọ fun iwa mimọ yẹ ko le e jẹ Alufaa, lati le e fun awọn eniyan to wa ni igberiko lanfaani lati le ni Alufaa ninu ijọ.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Àwọn tó bu ẹnu àtẹ́ lu ìgbésẹ̀ náà ní yóò fòpin sí òdodo àti ìwa mímọ́ àwọn àlùfáà Ijọ Aguda,èyì tó jẹ́ ìpìnlẹ̀ ìjọ náà.

Ki ipinnu naa to wa si imusẹ, Olori Ijọ Aguda lagbaye, Poopu Francis gbọdọ bu owo lu igbesẹ naa, ti awọn eniyan naa si woye pe, o yẹ ki Poopu Francis naa sọ ero rẹ lori idibo naa, ki ọdun yii to pari.