DNA àwọ̀tẹ́lẹ̀ Abu Bakr al-Baghdadi tí wọ́n jí ló ṣekú pa á

Abu Bakr al-Baghdadi

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Abu Bakr al-Baghdadi pa ara rẹ ninu akọlu ti ilẹ Amẹrika ṣe sagbe to farapamọ si

Ẹgbẹ ọmọ ogun Syria, SDF, ti sọ pe alami kan ti wọn bẹ lọwẹ lo ji awọtẹlẹ Abu Bakr al-Baghdadi, to jẹ olori ẹgbẹ agbesunmọmi Islamic State ki ọwọ to tẹ ẹ.

O ni ẹgbẹgun naa ṣe ayẹwo DNA awọtẹlẹ naa, lati fi mọ daju pe ti al-Baghdadi ni, ati pe oun ni ẹni ti wọn fẹ doju kọ ki wọn to gbeja lọ agbegbe to farapamọ si.

Alukoro agba ninu ẹgbẹgun ọhun, Polat Can sọ pe, ami naa ṣe iṣẹ takuntakun lati ṣe awakan agbegbe ti ile al-Baghdadi wa, ki awọn ọmọ ogun ilẹ Amẹrika to ṣọṣẹ lagbegbe ọhun.

Nigba ti awọn ọmọ ogun Amẹrika n ṣọṣẹ naa ni al-Baghdadi gba ẹmi ara rẹ, ṣugbọn aarẹ Amẹrika, Donald Trump ti fẹnu tẹmbẹlu ipa ti ẹgbẹgun Kurd ko ninu ija naa.

Nigba ti aarẹ Trump n royin igbogunti ọhun, o ni awọn ẹgbẹgun Kurd ṣeranlọwọ diẹ fun awọn ọmọ ogun Amẹrika, ṣugbọn wọn ko kopa ninu ija ti al-Baghdadi di oloogbe.

Ṣugbọn ọgbẹni Polat Can sọ ninu ọrọ to fi lede loju opo Twitter rẹ pe, SDF kopa to laami laaka ninu ija naa.

Can fikun pe, ẹgbẹgun SDF ti n ṣiṣẹ pẹlu ajọ ọtẹlẹmuyẹ CIA ilẹ Amẹrika lati ọjọ karundinlogun oṣu karun un ọdun 2019.

O ṣalaye pe ninu ajọṣepọ ẹgbẹgun SDF ati CIA ni wọn ti ṣawari agbegbe ibi ti al-Baghdadi n gbe ni Idlib, lorilẹ-ede Syria.

Àkọlé fídíò,

Owu Water Fall: Ọba Oyewole ni ibùdó ìrìn àjò afẹ́ gidi ni àmọ́ ọ̀nà ibẹ̀ burú jáì