Twitter: Njẹ́ o dára bí olùdásílẹ̀ Twitter ṣé fẹ fòfin dè ìpolongo òṣèlú lójú òpó rẹ́?

Aworan idanimọ Twitter

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Eniyan 330 Millionu lo n lo oju opo ikansiraẹni Twitter

Ile iṣẹ opo ikansiraẹni lori ayelujara, Twitter ti lawọn ṣetan lati fofin de gbogbo ipolongo to ni ṣe pẹlu ọrọ oṣelu loju opo wọn.

Jack Dorsey to jẹ ọga ile iṣẹ naa ni o yẹ ki awọn eeyan ṣiṣẹ tọ ki wọn lee dii ilumọọka sọ pe yatọ si bi wọn ti ṣe n fowo ra idanimọ pẹlu ipolongo ti wọn n san owo fun.

"Ipolowo loju opo ayelujara lagbara gaan ti a si maa mu anfaani wa fawọn to n polowo ọja ṣugbọn iru agbara bẹẹ le ṣakoba fun iṣe oṣelu''

Ikede fifofin de ipolowo yii ti n mu iwoye ọtọọtọ wa paapa julọ fawọn to fẹ kopa ninu idibo aarẹ ilẹ Amẹrika to n bọ lọdun 2020.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Brad Parscale, to jẹ oludari ipolongo aarẹ Donald Trump ni ọna a ti pa awọn alatilẹyin aarẹ Trump lẹnu mọ ni igbesẹ yii.

Ṣugbọn Bill Russo to n gbẹnusọ fun ipolongo oludije Joe Biden ti ẹgbẹ Democrat sọ pe ''Bi a ba n wa owo lọ taa pade iyi lọna, owo ko le bori''

Ofin to de ipolongo yi yoo fẹsẹ mulẹ lọjọ kejilelogun oṣu Kọkanla ọdun 2019 ti wọn yoo si fi ẹkunrẹrẹ iroyin nipa rẹ sita lọjọ kẹẹdogun oṣu Kọkanla.

Ipa wo ni yoo ni lagbo oṣelu Naijiria?

Kayode Ogundamisi to jẹ onwoye nipa oṣelu Naijiria ṣalaye fun BBC pe igbeṣẹ yi bojumu lati le koju iroyin ofege eleyi tawọn oloṣelu a maa saba lo lasiko ipolongo idibo.

''Bi a ko ba gbagbe pe aṣiri tu laipẹ bi ile iṣẹ Cambridge Analytica ṣe n ṣagbatẹru ipolongo iroyin ofege lasiko idibo eleyi ti o fẹ ṣakoba fun idibo Naijiria lọdun 2015''

Àkọlé fídíò,

Wo ọna ti o le gba lati fi daabo bo ara rẹ lori Facebook.

O tẹsiwaju pe ''Ti a ko ba dẹkun iru iwa bayi, awọn kan yoo kan maa pawo ipolongo lalai bikita ipa ti yoo ni lori ara ilu. Kayode ni "Inu mi dun si oun ti Twitter fẹ ṣe yi''

Ẹwẹ oju opo kan lara awọn to n figagbaga pẹlu Twitter, Facebook naa ti kede pe awọn yoo fofin de ipolongo to ni ṣe pẹlu oṣelu loju opo ti wọn naa.

Àkọlé fídíò,

Àwọn ọkùnrin tó wà nínú ayé wa gbúdọ̀ bọ̀wọ̀ fún wa - Adarí FIN

Mark Zuckerberg to jẹ ọga ileeṣẹ Facebook lo sọ ọrọ yi fawọn oniroyin.

O ni oun o lero pe o yẹ ki awọn ileeṣẹ aladani maa tọ pinpin iroyin oṣelu tawọn eeyan n gbọ nitori owo.

Àkọlé fídíò,

Àṣà àti ìgbàgbọ́ Yorùbá ni pé òbí wọn máa ń padà wá sáyé