Nigerian students in Bosnia: Ìjọba ṣetán láti kọ̀wé ẹ̀sún sí EU,UN àti HRC

Abike Dabiri-Erewa

Oríṣun àwòrán, NIDCOM

Ijọba orilẹede Naijiria ti sọ fun BBC pe oun yoo kọwe kotẹmilọrun si ajọ ilẹ Yuroopu, EU ti orilẹede Bosnia ba fi kọ lati fi awọn akẹkọọ Naijiria meji ti wọn fi sahamọ ranṣẹ sile ni ọsẹ yii.

Alaga ajọ to wa fun ọrọ awọn ọmọ Naijiria nilẹ okeere, NIDCOM, Abike Dabiri-Erewa, sọ pe ọjọ kẹtalala oṣu Kejila ni wọn da pe wọn yoo da wọn pada sile ṣugbọn titi di ọjọ kejidinlogun, ko ti si nkan to jọ bẹ ẹ.

Awọn akẹkọọ naa sọ pe awọn alaṣẹ Croatia ṣe aṣiṣe ni wọn fi le awọn lọ si orilẹede Bosnia, lẹyin idije bọọlu gbigba ori tabili (table tennis) ti awọn rinrinajo lọ lati kopa.

Arabinrin Dabiri-Erewa sọ pe oun ti ba awọn akẹkọọ mejeeji, Alexandro Abia ati Kenneth Eboh sọrọ, ati pe ipo ti wọn wa ko dara rara.

O sọ pe koda, ọkan lara wọn daku ni ibudo ti wọn fi wọn si ni Bosnia.

"A ko le gba iru nkan bẹ ẹ."

Awijare Abia ati Eboh ni pe awọn alaṣẹ orilẹede naa fi wọn pe arinrinajo lọna aitọ, ti wọn si le wọn jade lọ si Bosnia ninu oṣu Kejila.

Ṣugbọn ijọba Croatia sọ pe ọrọ ko ri bẹ ẹ.

Àkọlé fídíò,

Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n Yorùbá foríkorí gbé ìwé tó lè sọ ẹ̀yà ara yín lédè Yorùbá.

Abike Dabiri fidirẹmulẹ pe awọn akẹkọọ mejeeji ni iwe irinna lọwọ, wọn ko si ti i lo ju iye ọjọ to yẹ ki wọn o lo. Nitori naa, ko yẹ ki Croatia o le wọn jade.

"Ireti wa ni pe wọn yoo pada sile ni ọsẹ yii. Ti ko ba wa ri bẹ ẹ, ao kọ iwe kotẹmilọrun si ajọ EU, UN, ati ajọ ajafẹtọ ọmọniyan. Croatia ati Bosnia ko ni ẹtọ lati fi awọn akẹkọọ wa si ihamọ.