Sotitobire church: Ẹgbẹ́ CAN ní kí ìjọba ṣe ohun tó yẹ

Sotitobire church: Ẹgbẹ́ CAN ní kí ìjọba ṣe ohun tó yẹ

Alaga apapọ ẹgbẹ awọn ọmọlẹyin Kristi nipinlẹ Ondo, CAN, Ọmọwe John Ayọ Ọladapọ naa ti dasi awuyewuye ti o rọ mọ ọmọ ọdun kan ti o dede poora nile ijọsin Sọtitobirẹ to n bẹ nilu Akure.

Lasiko to n ba ikọ BBC Yoruba sọrọ l'Ọjọbọ, Ọladapọ ṣe alaye wi pe Alfa Babatunde ti o jẹ oludasilẹ ile ijọsin naa kii ṣe ọmọ ẹgbẹ ajọ CAN nipinlẹ Ondo, eyii lo si mu ki o nira fun ajọ naa lati dasi ohun ti ko kan wọn.

O tẹsiwaju wi pe ijọba nikan lo ni aṣẹ lati tu iṣu de isalẹ ikoko lori ọrọ naa.

Ọjọru ni awọn araalu dana sun ile ijọsin naa lẹyin ti iroyin kan jade pe wọn ri oku ọmọ dun kan, Gold, to di awati nile ijọsin naa ni nkan bi oṣe meji sẹyin.