Olùkọ́ fásitì gba ìdájọ́ iku 'torí pé ó sọ̀rọ̀ òdì sí Ànọ́bí lórí ayélujára

Kuraani

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Olukọ fasiti kan ni Pakistan ti gba idajọ iku fun ẹsun ọrọ odi sisọ.

Wọn fi panpẹ mu Junaid Hafeez, ẹni ọgbọn ọdun le mẹta, l'oṣu Kẹta, ọdun 2013, ti wọn si fi ẹsun kan an pe o kọ awọn ọrọ arifin nipa Anọbi Muhammaed lori ẹrọ ayelujara.

Kii ṣe ọwọ kekere ni wọn fi maa n mu ẹsun ọrọ odi sisọ ni Pakistan.

Agbẹjọro to kọkọ fẹ ẹ ṣ'oju Hafeez, Rashid Rehman, ni awọn kan yinbọn pa ni ọdun 2014 lẹyin to gba lati gba ẹjọ rẹ wi nile ẹjọ.

Àkọlé fídíò,

'Mo fara da ìsòro gan láwùjọ́ torí àwọn òbí mi di létí'

Olukọni naa ti lo ọpọ ọdun ninu ẹwọn ti oun nikan wa, lẹyin ti awọn ẹlẹwọn yooku kọlu leralera.

Orilẹede Amẹrika ni Hafeez ti kawe, ko to o pada si Pakistan. Lẹyin naa lo si bẹrẹ iṣẹ olukọni ni Fasiti Bahauddin Zakariya, nilu Multan, titi di igba ti wọn fi ofin gbe e.

Botilẹjẹ wi pe agbẹjọro rẹ bayii, Asad Jamal sọ fun ileeṣẹ iroyin AFP pe awọn yoo pe ẹjọ kotẹmilọrun, niṣe ni awọn agbẹjọro to rojọ tako Hafeez n pin nkan ipanu fun awọn akẹgbẹ wọn, to n pariwo "Allahu Akbar" ati "iku ni fun awọn to ba sọrọ odi".

Ajọ ajafẹtọ ọmọniyan l'agbaye, Amnesty International, ti ṣapejuwe idajọ naa gẹgẹ bi nkan to yanilẹnu, to si bani lọkan jẹ.