Bàbá oníṣòwò kan san owó iná àwọn aládùúgbò rẹ 36 gẹ́gẹ́ bi ẹ̀bùn ọdún

Igi ọdun Keresimesi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ọgbẹni Esmond sọ fun BBC pe iriri ti oun ni lasiko kan sẹyin, lo fun oun ni iwuri lati ṣe nkan ti oun ṣe.

Baba agba ẹni ọdun mẹtalelaadọrin kan, ti fi ọrọ rẹ ṣe ẹnikẹni ti iwọ ba nipa lati ṣe iranlọwọ fun, oun naa lẹnikeji rẹ, tọju rẹ.

Niṣe lo san san owo ina awọn aladugbo rẹ mẹrindinlogoji.

Michael Esmond to jẹ oniṣowo, to ni ileeṣẹ kan to maa n gbẹ odo iwẹ igbalode (swimming pool) nilu Florida sọ pe lẹyin ti oun gba iwe iye owo ina ti oun yoo san , ni eero naa sọ si oun lọkan pe ko buru ti oun ba "mu itura ba awọn aladugbo oun."

Bi Esmond ṣe lọ san owo ina ati omi rẹ fun oṣu yii, lo ba ri ikilkọ ti wọn lẹ mọ ibikan pe wọn yoo ja ina gbogbo awọn ti ko ba san owo wọn ko to o di ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Kejila.

O ni l'oun ba pe awọn alaṣẹ agbegbe ti oun n gbe, Gulf Breeze, ni ibẹrẹ oṣu yii pe ṣe oun le san owo gbogbo awọn to jẹ wọn lowo ni agbegbe oun.

Àkọlé fídíò,

Ondo disability day: Ijọba ẹ gbà wá ní ariwo tí àkàndá ẹ̀dá ń pa

Ọgbẹni Esmond sọ fun BBC pe iriri ti oun ni lasiko kan sẹyin, nigba ti oun ko ri itan tan ẹrọ amule-mooru lo fun oun ni iwuri lati ṣe nkan ti oun ṣe.

Esmond fi kun un pe igba kan wa ni nkan bi ọdun 1980, ti oun ko ni ina lasiko otutu. O sọ pe asiko naa si ni igba otutu to buru ju ti oun ti ri ri.

Apapọ owo to jẹ ẹgbẹrun mẹẹrin o le ẹgblta Dọla($4,600) ni Esmond fi san gbese fun idile mẹrindinlogoji ni agbegbe rẹ.

Àkọlé àwòrán,

Esmond sọ pe o ya oun l'ẹnu nigba ti ipe oriṣiriṣi bẹrẹ si ni wọ ori ẹrọ ibaraẹnisọrọ oun.,

Esmond ko sọ fun awọn ẹni naa pe oun ti san gbese wọn. Igba ti ipe oriṣiriṣi n wọ ori ẹrọ ibaraẹnisọrọ rẹ lati dupẹ lọwọ rẹ lo to o mọ wi pe awọn alaṣẹ ilu naa kọ nkan to ṣe sinu kaadi ikini ku ọdun ti wọn fi ranṣl si awọn araadugbo rẹ.

Ni bayii, ọpọ eniyan lo ti ṣe ileri ohun ti awọn yoo tete maa san owo ina awọn, ti awọn naa yoo si ṣ'oore fun ẹlomiran, nitori pe ihuwasi Esmond wu awọn lori.