Pope Election: Èyí ni bí wọ́n ṣe n dìbò yan Póópù tuntun nínú ìjọ Àgùdà

ilẹkun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ilekun ile mimọ ti awọn eeyan ti n jọsin

Igbimọ awọn cardinal wa to maa n pejọpọ lati dibo yan Poopu tuntun.

Awọn cardinal ni awọn olóyè ijọ to tobi ju. Poopu lo maa n yan wọn si ipo, wọn si ṣaba maa n jẹ oye biṣọọpu.

Wọn yoo pe wọn si ipade ni olu ijọ Aguda, to wa ni Vatican, idibo yoo si tẹle e- 'conclave' ni wọn maa n pe eto idibo naa.

Awọn cardinal bi igba le mẹta lati orilẹ-ede mọkandinlaadọrin lo wa. Ẹni to ba si ti dagba ju ọgọrin ọdun lọ laarin wọn ko le dibo.

Àkọlé àwòrán,

Inu ile ijọsin Sistine ti idibo ti maa n waye.

Ìkọ̀kọ̀ ni ìdìbò nàá ti n wáyé:

Wọn maa n ṣe eto idibo naa ni ayika to pamọ.

Niṣe ni wọn maa n ti awọn Cardinal naa mọ ibi kan, ni olu ijọ Aguda, Vatican to wa ni ilu Rome l'orilẹ-ede Italy,

Àkọlé fídíò,

Christmas:Ṣé ẹ ti ra fìlà ọdún?

Ko si si ẹnikẹni ninu wọn ti yoo bọ si jade bọ si gbangba titi eto idibo naa yoo fi pari, ti wọn si fẹnuko lori Poopu tuntun.

Ko pọn dandan ki awọn cardinal naa o yan ọkan lara wọn - ninu akọsilẹ, ọkunrin ijọ Aguda yoo wu to ba ti ṣe iribọmi ni wọn le yan ni poopu - ṣugbọn àṣà sọ pe cardinal ni wọn yoo fẹ ẹ gbe e fun.

Àkọlé fídíò,

Parental Guidance: Ọdún méjì ni kí ẹ ti bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ọmọ nípa ìbálòpọ̀

Eto idibo yii maa n waye fun ọpọlọpọ ọjọ ko to o dipe Poopu tuntun jẹ.

Wọn maa n wa ni ipamọ; ko si nkan to jọ tẹlifisan, radio, iwe iroyin tabi ẹrọ ibaraẹnisọrọ.

Dokita meji pere, awọn to n tun ile ṣe ati awọn alufaa to ni ẹtọ lati gbọ ijẹwọ ẹṣẹ awọn eniyan ni oriṣiriṣi èdè nikan ni anfaani wa fun lati wọ inu ibi ti wọn wa.

Àkọlé fídíò,

Christmas: Jesu ni ọjọ́ ọ̀la àti ibi ìyanu mi- Jaga

Koda, awọn dokita ati awọn oṣiṣẹ to ku gbọdọ bura pe ọrọ kankan nipa idibo naa ko ni i ti ẹnu awọn jade, tabi lo ẹrọ ayaworan ati gbohun-gbohun.

Gbogbo eyi n waye, ki aṣiri kankan nipa idibo naa ma ba a tu sita lasiko to n lọ lọwọ tabi to ba pari. Ti ikilọ si wa pe wọn yoo yọ ẹnikẹni to ba sọrọ jade l'ẹgbẹ.

Àkọlé fídíò,

Christmas: Ẹni ti ọdun ba ti bá láyé yẹ kó dúpẹ́

Bí ètò ìdìbò ṣe n wáyé

Gbọngan ile isin Sistine Chapel ni eto idibo naa ti maa n waye, "nibi ti ohun gbogbo ti faaye gba iwa laaye Ọlọrun, niwaju ẹni ti gbogbo eniyan yoo ti gba idajọ ni ọjọ kan".

Lọjọ ti eto idibo naa ba fẹ ẹ bẹrẹ, awọn cardinal naa yoo ṣe Isin ni owurọ, ki wọn o to to o wọle sinu ijọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Eyi ni àwo ti wọn maa n ko iwe idibo si ninu

Ni kia ti wọn ba si ti wọleni wsn yoo bura lati pa aṣiri gbogbo mọ. Lẹyin naa ni ẹnikan yoo paṣẹ fun gbogbo awọn ti ko ni i kopa ninu idibo lati jade sita ki wọn o to o ti ilẹkun.

Awọn cardinal naa ni oore-ọfẹ lati mu iwe idibo kan pere dani ni ọsan ọjọ akọkọ. Lati ọjọ keji, iwe idibo meji ni wọn yoo mu dani owurọ, ati meji ni ọsan.

Igun mẹrin ni iwe idibo naa ni. Wọn si ti tẹ ọrọ yii "Eligio Summum Pontificem" ("Mo dibo yan Alufaa to tobi ju lọ"), si apa oke.

Isalẹ ni aaye wa lati kọ orukọ ẹni ti wọn ba yan si.

Wọn si maa n paṣẹ fun awọn cardinal naa lati kọ orukọ ẹni naa ni ọna ti ẹnikẹni ko le mọ wi pe awọn ni wọn kọ ọ, ki wọn o si ka iwe pelebe naa lẹẹmeji.

Àkọlé fídíò,

Ohun mẹ́jọ tóo ní láti mọ̀ bí o bá fẹ́ lọ ilé ọdun

Ti wọn ba ti dibo tan, wọn yoo da gbogbo awọn iwe pelebe naa pọ, wọn yoo ka a, wọn yoo si ṣi wọn.

Ẹni kan lara awọn to n woye yoo maa pe orukọ cardinal kọọkan ti wọn dibo fun bi wọn ba ṣe n ka awọn iwe pelebe naa.

Yoo si fi abẹrẹ gun iwe kọọkan lati fi okun kan pere de wọn pọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Eefin to n jade ni ori ile nikan ni apẹrẹ pe idibo n lọ lọwọ ninu ile

Lẹyin eyi ni wọn yoo dana sun awọn iwe naa - eefin rẹ yoo si han si awọn to n woran ni ita. Eefin naa maa n yipada lati dudu si funfun ni kete ti wọn ba yan poopu tuntun.

Wọn maa n da koriko tutu mọ aro ti wọn fi n dana sun wọn, lati le mu eefin naa dudu. Sugbọn, lati bi ọdun melo kan si asiko yii, awuyewuye n wa lori àwọ eefin naa. Aró ni wọn n lo bayii.

Àkọlé fídíò,

Ǹkan tí ẹ̀mí mímọ́ fi hàn mí kí n tó bẹ̀rẹ̀ orin ìfèdèfọ̀ rèé- Testimony Jaga

Bi eto idibo keji yoo ba waye, wọn yoo ko awọn iwe idibo akọkọ si ẹgbẹ kan, wọn yoo si dana sun wọn papọ mọ ti idibo keji. Bayii ni wọn yoo ṣe titi ti oludije kan yoo fi ni ibo to pọ ju.

Àkọlé fídíò,

Àwọn aránṣọ yarí pé gbogbo ẹ̀bi kìí ṣe tàwọn, díẹ̀ wà lọ́wọ́ àwọn oníìbárà náà

Fifi ẹnu ko

Nini ilana idibo naa, oludije gbọdọ ni ida meji ninu ida mẹta ibo ki wọn o to kede rẹ pe o wọle (ida meji naa yoo le ẹnikan, ti iye awọn cardinal to dibo ko ba ṣe e pin si mẹta).

Bi ẹnikẹni ko ba ni ìdá meji lẹyin ọjọ kẹta, wọn yoo da idibo duro fun ọjọ kan lati faaye silẹ fun adura gbigba, ijiroro ati "iwaasu ranpẹ" lati ẹnu cardinal ti oyè rẹ ga ju.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Awọn eniyan n ho fun ayọ nigba ti wọn ba kede poopu tuntun

Lẹyin eto idibo, wọn yoo kọ awọn esi ibo sinu iwe kan, wọn yoo si gbe e le poopu tuntun lọwọ.

Wọn yoo fi pamọ si ibi kan ninu apo iwe ti wọn lẹ pa, eyi ti wọn ko le ṣi ti poopu ko ba paṣẹ rẹ.

Eefin to n jade lati inu ile lasiko ti wọn n dana sun iwe idibo nikan ni àmì pe idibo n lọ lọwọ.

Ikede Poopu tuntun

Ni kete ti oludije kan ba ti ni ìdá meji ibo, wọn yoo beere lọwọ rẹ pe: "Ṣe o faramọ iyansipo rẹ gẹgẹ bi poopu Alufaa to ga ju?"

To ba si ti sọ pe bẹẹni, wọn yoo sọ fun un pe ko yan orukọ to fẹ ki wọn o maa pe e.

Lẹyin to ba ti yan orukọ kan, awọn cardinal to ku yoo sun mọ poopu tuntun lati fi ori balẹ fun un.

Poopu tuntun yoo wọ aṣọ oye rẹ. Aranṣọ awọn poopu ti maa n ran awọn aṣọ naa silẹ fun ẹni to sanra tabi ti ko sanra - ṣugbọn wọn le ṣe atunṣe pajawiri si i.

Lati iwaju ita ijọ Peteru Mimọ (St Peter's Basilica) ni wọn yoo ti kede pe: "Annutntio vobis gaudium magnum... habemus papam!" - "Mo kede ayọ nla fun un yin...a ti ni poopu tuntun!"

Àkọlé fídíò,

Christmas & Border Closure: ìrẹsì dí góòlù fún Kérésì 2019

Lẹyin naa ni wọn yoo kede orukọ rẹ, poopu tuntun naa yoo si jade si gbangba fun igba akọkọ.

Yoo sọ ọrọ diẹ, yoo si gba adura ibukun Urbi et Orbi - "si ilu yii ati si aye".

Àkọlé fídíò,

Ǹjẹ́ o mọ pàtàkì igi tó wà ní àyíká rẹ bí?