2020: Oloye Awurela Ifaleke ti wúré ọdún ìgbéga fún kóówá

Oloye Ifaleke Awurela Amufawuni to jẹ oludasilẹ ijọ Orunmila Apapọ Odu wure ọdun 2020.

Ifa ni òdídí a dí ire owo, ire ọmọ, ire ara lile, ire igbega ni gbogbo ọna sinu aye gbogbo ẹyin ololufẹ BBC.

Odun tuntun tun ti wọle de wẹrẹ, ki onikaluku gbajumọ iṣẹ aje kan tabi omii.

Yoruba ni Atẹlẹwọ ẹni kii tan ni jẹ, bẹẹ iṣẹ ti a ba n ṣe ni Eleduwa a fi ibukun si

Ninu ọdun tuntun yii, ki onikaluku jawọ ninu ohunkohun ti a ba n ṣe ni 2019 ti ko dara.

Olodumare to mọ irinajo ẹda laye a ba gbogbo wa rin irnajo ọdun 2020 yii layọ ati alaafia lai fi ẹsẹ kọ.