First Temptation of Christ: Ilé ẹjọ́ pàṣẹ kí Netflix dáwọ́ fíímù Jesu tó n ní ìbálòpọ̀ akọ s'ákọ dúró

Aworan lati ara fiimu ti ẹgbẹ apanilẹrin Porta dos Fundos ṣe fun ọdun Keresi : Christ's First Temptation Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Fiimu naa ṣe ṣafihan pe Jesu mu 'ọrẹkunrin' rẹ wa sile lati mọ ẹbí rẹ.

Ile ẹjọ kan l'orilẹede Brazil ti dajọ pe ki ileeṣẹ to n ṣafihan fidio lori ayelujara, Netflix, yọ fiimu to ṣafihan Jesu gẹgẹ bi ẹni to n ni ibalopọ akọsakọ, kuro loju opo ayelujara wọn.

Fiimu naa, 'The First Temptation of Christ', to tumọ si 'Idanwo Akọkọ Jesu', mu ki inu bi awọn kristẹni kan l'orilẹ-ede naa ati kaakiri agbaye.

Ọmọ Nàìjíríà bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu iléeṣẹ́ Netflix lórí fíìmù tó ní Jesu ní ìbálòpò akọ s'ákọ

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMike Ifabunmi: Òrìṣà ló gbè wà jù ni Brazil

Miliọnu meji eniyan lo si bu ọwọ lu u pe ki wọn o da fiimu naa duro, awọn eniyan kan si kọlu ileeṣẹ naa l'oṣu to kọja.

Ninu idajọ ọhun to ta ko Netflix, adajọ naa sọ pe: "Ẹtọ lati sọ ohun to wu ọ... ko fun ọ ni gbogbo agbara".

Akọroyin BBC, Daniel Gallas jabọ iroyin lati Sao Paulo pe "Onidajọ Benedicto Abicai sọ pe ki ileeṣẹ Netflix yọ fiimu naa kuro lori ayelujara rẹ".

Adajọ sọ pe ofin ti wọn fi de fiimu naa fun igba diẹ yoo jẹ ki ibinu awọn Kristẹni to n binu si fiimu naa o walẹ, titi ti ile ẹjọ miiran to ga ju u lọ yoo fi ṣe idajọ to kẹhin.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionHelgies Bandeira: Ọ̀pọ̀ oúnjẹ Yorùbá ni à ń jẹ ni Brazil

Ṣugbọn ṣa, ko tii si eyi to f'esi lori idajọ naa laarin Netflix ati ẹgbẹ apanilẹrin Porta dos Fundos.

Kilo mu ki awọn eniyan o binu si fiimu naa?

Ẹgbẹ apanilẹrin kan to n lo ayelujara Youtube ni Brazil, Porta dos Fundos, lo ṣe fiimu apanilẹrin naa jade, ti wọn si ṣe afihan rẹ lasiko ọdun Keresi to kọja.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionHelgies Bandeira: Ọ̀pọ̀ oúnjẹ Yorùbá ni à ń jẹ ni Brazil

Awọn Kristẹni kan l'orilẹede naa binu si bi fiimu ọhun ṣe ṣafihan pe Jesu mu 'ọrẹkunrin' rẹ wa sile lati mọ ẹbí rẹ.

Ni alẹ aisun ọdun Keresi, ẹgbẹ kan kọlu ileeṣẹ Porta dos Fundos to wa ni Rio de Janeiro, pẹlu ado oloro.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ apanilẹrin Porta dos Fundos ti gba awọn ami ẹyẹ l'agbaye

Ọkunrin kan ti wọn fura si pe o lọwọ ninu ikọlu naa ti salọ si Russia, awọn ọlọpaa agbaye 'Interpol' si ti n wa a.

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí