Libyan conflict: Wo ohun tó yẹ ko mọ̀ nípa ogun abẹ́lé ní Libya

Awọn ọmọ ologun Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Ogun abẹle orilẹ-ede Libya bẹrẹ lẹyin iku aarẹ Muammar Gaddafi

Lati igba ti ogun abẹle Libya ti bẹrẹ ni nnkan bi ọdun mẹwaa sẹyin ni awọn orilẹ-ede kaakiri agbaye ti n wa ọna lati pana ogun naa.

Lọwọ yii, awọn igun meji lo n ṣejọba lorilẹ-ede Libya, akọkọ ni eyii ti ajọ iṣokan agbaye lọwọ si, ti aṣoju ijọba Fayez al-Serraj n dari, ekeji ni ẹgbẹ ajijagbara ti ọgagun Khalifa Haftar ko sodi.

Laarin ọsẹ yii ni awọn igun mejeji fẹnuko lati dawọ ogun duro fun igba diẹ, lẹyin akitiyan orilẹ-ede Russia ati Turkey.

Ṣugbọn lẹyin ọjọ melokan sii, ni ija tun bẹrẹ latari bi ọgagun Haftar ṣe kọ lati ṣe ojuse to rọ mọ adehun didawọ ogun naa duro.

Ṣugbọ bawo ni ọrọ naa ṣe bẹrẹ gan?

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Turkey ati Russia n fẹ lati lee paṣẹ lori ọjọ iwaju Libya

Bi ọrọ ṣe bẹrẹ ree:

Ija naa bẹrẹ pẹlu rogbodiyan to waye lawọn orilẹ-ede larubawa, ti ọpọ mọ si 'Arab spring' lọdun 2011.

Lọdun naa lọhun, awọn ọmọ ogun ti ajọ NATO n ṣatilẹyin fun gbajọba lọwọ aarẹ ọlọdun gbọọrọ lorilẹ-ede naa, Muammar Gaddafi.

Igbesẹ naa, eyi ti ọpọ awọn ọmọ ilẹ Libya atawọn mii lorilẹede agbaye lero pee yoo ṣe anfani nla fun orilẹede ọhun, ṣugbọn ọrọ bẹyin yọ.

Lati ọdun naa lọhun ni wahala ti bẹrẹ lorilẹede Libya titi di akoko yii.

Lẹyin ọpọ ọdun ti ogun naa ko dawọ duro, ajọ agbaye gbiyanju ati gbe ijọba kan kalẹ ki alaafia lee jọba, eyii ti aṣoju ijọba Serraj n tukọ ni olu ilu orilẹede ọhun, Tripoli.

O ṣeni laanu pe ọpọ awọn eeyan ni ko nifẹ si ijọba naa, ati pe ọgagun Haftar ni tirẹ naa n fẹ lati jẹ olori ijoba.

Idi naa lo ṣe da ẹgbẹ ọmọ ogun tirẹ silẹ, eyii to pe ni ẹgbẹ ọmọ ogun ilẹ Libya, to ni oun fẹ lo lati fi le awọn ẹgbẹ agbesumọmi Musulumi lare.

Lati igba naa ni awọn ọmọ ogun ọgagun Haftar ti n gbiyanju lati gba Tripoli lati oṣu Kerin ọdun 2019, ṣugbọn loṣu kinni ọdun yii lo ṣaṣeyọri lati gba ipinlẹ Sirte.

Ọrọ naa di iṣu ata yanyan nigba ti awọn ajijagbara kekeke mii bẹrẹ si n gberi, ti wọn si n ja ija tiwọn, ẹgbẹ Islamic State naa tun da kun wahala ọhun.

Awọn ogun aṣoju

Awọn to n gbiyanju ati gbajọba orilẹede Libya kii ṣe awọn ologun ninu orilẹede ọhun nikan, awọn alagbara mii lati awọn orilẹede agbaye naa lọwọ si ogun naa.

Eyi to tumọ si pe awọn igun meji to n ṣakoso ilẹ naa lọwọ, lo ni awọn orilẹede to jẹ alatilẹyin fun ikọọkan wọn.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ọgagun Khalifa Haftar ti mu awon alagbara lagbaye gẹgẹ bi igi lẹyin ọgba

Fun apẹrẹ, UAE ati Saudi Arabia ni wọn fẹ le awọn ẹgbẹ ogun Musulumi kuro lagbegbe ọhun, orilẹede Jordan naa ti n pese awọn ohun ija fun awọn ọmọ ogun ilẹ naa, ti aṣoju ijọba Fayez al-Serraj n dari.

Ni ida keji ẹwẹ, orilẹede Egypt n ṣatilẹyin fun ikọ ọgagun Haftar, o si n pese ohun ija fun wọn bakan naa.

Ibi ọrọ de duro:

Oriṣiriṣi awọn ẹlẹgbẹjẹ lo lọwọ si ogun abẹle orilẹede Libya, idi ni pe orilẹede naa lo ni epo bẹntiro to pọ ju nilẹ Afrika.

Libya tun jẹ ọkan gboogi ninu awọn ọna ti awọn ọmọ ilẹ Afrika ma n gba lọ ṣe atipo nilẹ Yuroopu.

Awọn onwoye ohun to n lọ lagbaye ti wa sọ pe, bi ogun Libya ba tẹsiwaju, o ṣeeṣe ki rogbodiyan naa tan lọ si awọn orilẹede mii to wa ni ayika rẹ.

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí