Orthodox Christians Epiphany: Àwọn krìstíẹ́ní yìí n wẹ̀ nínú omi tútù fún àjọyọ̀ ìrìbọmi Jesu

Awọn olujọsin kaakiri Russia ati Ila oorun Yuroopu ti n 'jare ọyẹ' pẹlu bi wn ṣe n wẹ ninu odo ti omi rẹ ni yìnyín, fun ajọyọ ifihan Jesu (Epiphany).

Ọkan pataki ni lara awọn ọjọ isinmi ninu kalẹnda awọn kristiẹni igbagbọ atijọ.

Ajọyọ naa to maa n waye ni ọjọkọkandinlogun, oṣu Kinni, maa n wa fun iranti iribọmi Jesu, ninu odo Jọdaani.

Presentational white space
Alufaa kan n ṣe eto iyasọtọ fun olujọsin kan. Image copyright Reuters

Lati ṣe ajọyọ ọjọ naa, ọpọlọpọ awọn Kristiẹni igbagbọ atijọ (orthodox) maa n ri ara a wọn sinu iho omi tutu.

Wọn le ki ara wọn sinu omi lẹẹmẹta lati bu ọla fun Mẹta-lọkan.

Alufaa ijọ igbagbọ atijọ kan n ya omi si mimọ ni Svyatoye lẹyin odi ilu Moscow ni Russia. Image copyright AFP

Igbagbọ wọn ni pe aṣa naa maa n mu ilera pipe wa fun awọn olujọsin, to si tun maa n wẹ ẹṣẹ wọn danu.

Ninu aworan oke yii, alufaa ijọ igbagbọ atijọ kan n ya omi si mimọ ni Svyatoye, to wa ni ẹyin odi olu ilu orilẹ-ede Russia, Moscow.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWo bi awọn alamojuto eto ṣe n pese iho yìnyín silẹ fun ajọyọ naa

Awọn olujọsin gbagbọ wi pe gbogbo omi maa n di mimọ ni ayajọ ifihan Jesu (Epiphany).

Awọn kan ti lẹ ro pe omi to tutu daadaa pẹlu yìnyín ni anfaani fun ilera.

Presentational white space
Ọkunrin kan n wẹ ninu odo adagun kan. Image copyright Reuters

Òyìnbó ẹni ọdún 46 wá ṣe mọ̀'mí n mọ̀ ọ́ ní Kano pẹ̀lú Isah olólùfẹ́ rẹ̀

Àwọn ọjọ́ ìsìnmi tó máa wà nínú ọdún 2020 ní Nàìjíríà

Ìlẹ̀kẹ̀ ìdí mi ló kó mi yọ lọ́wọ́ àwọn afipábánilòpọ̀ ní Lebanon

'A kẹ̀yìn sí Ivory Coast, owó yín ò lè máa jẹ́ "eco" táa ti mú fún àjọná owó ECOWAS'

Awọn onigbagbọ ijọ atijọ n bẹ sinu omi tutu oniyinyin ninu odo Sava, ni Belgrade. Image copyright AFP

Awọn olujọsin ijọ igbagbọ atijọ n bẹ sinu omi tutu oníyìnyín odo Sava nilu Belgrade.

Obinrin kan wọ inu omi lasiko ajọyọ ifihan Jesu ni Omsk Image copyright Reuters

Ninu aworan yii, obinrin kan n wọ inu omi nilu Omsk, l'orilẹ-ede Russia, nibi ti otutu ti n gba yayaaya lasiko yii.

Russia Ẹlẹwọn kan n ki ara rẹ bọ odo nilu Omsk. Image copyright Reuters

Ẹgbẹ́ kan fún Tinubu ní wákàtí mẹ́rìnlélógún láti sọ èrò rẹ lórí Amọtẹkun

Lalekan Ayọkunnu Are jáde láyé

Kínla! Ṣé olùkọ́ fásitì OAU míràn tún ti kó sí gbaga ìbálòpọ̀-fún-máàkì ni?

Ìtàn ìgbé ayé Bode Thomas rèé, ó kọ́ wa láti máa kó ẹnu wa ní ìjánu

Awọn to n ṣọ ẹlẹwọn n wo bi ẹlẹwọn kan ṣe n ri ara rẹ bọ omi ni ọgba ẹwọn alagbara kan to wa ni Omsk.

Awọn onigbagbọ ijọ atijọ ni Serbia n ya aworan Image copyright AFP

Awọn olujọsin korajọpọ lati ya aworan lẹyin ti wọn ti luwẹ tan ninu odo Sava, to wa ni ilu Belgrade.

Gbogbo aworan ti a lo lo ni orisun to ti wa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSuper touch: Roller Blader ni mí láti ọdún mẹ́jọ sẹ́yìn

Related Topics

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí