Ìgbésẹ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì láti mú ìdókoòwò pẹlú ilẹ̀ Áfríkà búrẹ́kẹ lẹ́yìn Brexit

Orilẹede Kenya

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ododo ni Orilẹede Kenya

Loni tii ṣe ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu Kini ọdun 2020 ni ilẹ Gẹẹsi yapa kuro ninu ajọ ilẹ Yuroopu, EU.

Lẹyin Brexit, ilẹ Gẹẹsi yoo ma wa ọna lati jẹ ki eto ọrọ aje burẹkẹ pẹlu ilẹ Afrika. Wọn ṣe ipade kan laipẹ nibi ti awọn olori orileede ilẹ Afrika ati ilẹ Gẹẹsi ti jọ pade ni London.

Njẹ ọrọ ti wọn le silẹ yii yoo mu ki karakata burẹkẹ?

Idokowo gba ọgbọn. Adehun karakata gaan ko dẹrun. Idunadura lati buwọlu adehun gaan ko rẹrin.

Kete ti ilẹ Gẹẹsiba fi EU silẹ, oṣu mọkanla pere lo ni lati ṣe agbekalẹ adehun pẹlu EU lati le ma ṣe pada si lilo ofin ajọ karakata agbaye WTO.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

As Foreign Secretary, Boris Johnson visited Ghana in 2017

Olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi Boris Johnson ati awọn alatilẹyin rẹ ko ye tẹnu mọ anfaani to wa ninu ki ilẹ Gẹẹsi da ṣe adehun idokoowo rẹ pẹlu awọn orileede miiran.

Ajumọṣe adehun eleyi to ṣe pe o ba ajọ EU wa ni anfaani ati aburu tirẹ naa.

Eeyan ni lati juwọlẹ lori awọn nkankan ni ibamu pẹlu ohun tawọn iyoku fẹ. O si tun nilo atilẹyin awọn ti ẹ jijọ pawọpọ lati ṣe idunadura rẹ.

Bawo lọrọ ṣe kan ilẹ Afrika?

Akọwe idagbasoke ilẹ okere fun ilẹ Gẹẹsi Alok Sharma ni oun ni igbagbọ pe karakata pẹlu ilẹ Afrika yoo gberasọ pẹlu bi awọn idokowo ṣe n ṣẹyọ lọtun losi.

Ijọba ilẹ Gẹẹsi ko fi ọrọ yi ṣere rara.

Ipade ti wọn ṣe pẹlu awọn olori ilẹ Afrika jẹ atọna si ipinu wọn.

Ayipada wo ni yoo waye ti ilẹ Gẹẹsi ba kuro ni EU?

Ko ni fẹẹ si nkan ti yoo yatọ nigba ti wọn ba kuro ni ipari oṣu kini ọdun.

Awọn alaṣẹ yoo sọ ọrọ to pọ ṣugbọn ilẹ Gẹẹsi yoo ṣi wa lara ẹgbẹ apapọ aṣọbode ti wọn yoo si jijọ maa na ọja kan naa titi di ipari ọdun.

Igbalaaye wa fun wọn lati ṣi wa nibẹ fun ọdun meji ṣugbọn olootu ijọba, Boris Johnson ti wọgi lee.

Eyi tumọ si pe idokowo laarin ilẹ Afrika ati ilẹ Gẹẹsi le bẹrẹ lọdun 2020 labẹ awọn ofin karakata EU ti wọn ti ṣe tẹlẹ pẹlu ilẹ Afrika.

Lẹyin 2020 nkọ?

Lẹyin ọdun 2020 o ṣeeṣe ki idunadura laarin awọn ilẹ Afrika ati ilẹ Gẹẹsi ṣi maa waye labẹ awọn adehun to ṣi n tẹsiwaju.

Ohun ti eleyi tumọ si ni pe awọn iwe adehun, idokowo ati adehun miran towa laarin awọn ilẹ Afrika, ẹgbẹ olokoowo ati ajọ EU yoo ṣi wa ni ṣẹpẹ.

Bi apẹẹrẹ loṣu kẹsan ọdun to kọja, ilẹ Gẹẹsi ṣe agbekalẹ ajọṣepọ owo kan pẹlu ẹgbẹ idokowo ẹkun guusu Afrika ti South Afrika, Botswana, Namibia Lesotho, Eswatini ati Mozambique wa lara rẹ.

UK's top African trading partners (2016). Trade volume $bn.  .

Wọn gbe igbesẹ yii ki nkan ba le wa bi o ti ṣe wa labẹ adehun idokoowo ti awọn orileede Guusu Afrika awọn yii ni pẹlu ajọ EU.

Ilana rẹ ko yatọ si eleyi ti EU ni nilẹ pẹlu Sacu.

Gẹgẹ bi ọrọ akọwe idokowo ilẹ okere ilẹ Gẹẹsi Liz Truss ti ṣe sọ, adehun yi yoo jẹ ki nkan ṣi wa bo ti ṣe wa tẹlẹ ''lalai mu idiwọ kankan wa lẹyin Brexit.''