Security Walk: Femi Emmanuel ni ìrìn fún ààbò dára àmọ́ kò le è tu irun kan lára ìjọba

ijọ Irapada

Oríṣun àwòrán, @RCCG_PR

Adari ẹgbẹ to n ja fẹtọ awọn Musulumi, MURIC, ọjọgbọn Ishaq Akintola ti sọ pe ẹgbẹ naa ko faramọ iwọde ti awọn ọmọlẹyin Kristi ṣe lodi si ọrọ eto abo to mẹhẹ lorilẹede yii.

Ishaq sọ fun BBC Yoruba pe, ko tọ fun olori ẹsin lati maa gbe patako lọwọ laarin igbooro, pe oun n ṣe ifẹhonuhan lodi si ijọba.

Ọjọgbọn naa ni iwọde ọhun da bi ẹni pe awọn to kopa ninu rẹ n ba ijọba ja ni, ati pe wọn ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu ni.

O ṣalaye pe, kaka ki awọn olori ẹsin maa gbe iwe ifẹhonuhan kiri, n ṣe lo yẹ ki wọn wo aarin ara wọn ki wọn si ṣe itaniji nitori awọn to n lọ ile ijọsin naa ni ọdaran.

Ishaq sọ si siwaju sii pe, awọn eeyan to kopa ninu iwọde naa jẹ alatako ijọba nitori wọn kii ri ohun rere ti ijọba n ṣe, ayafi eyii to ku diẹ kaato.

Oríṣun àwòrán, Sabonews1

Àkọlé àwòrán,

Akintola ni iwọde naa ko lee bi ọmọ rere

O ni iwọde naa ko lee bi ọmọ rere nitori n ṣe lo kọ awọn eeyan lati didie tako ijọba, ati pe ko kọ ijọba ni nnkan.

Ni tirẹ, Pasitọ Femi Emmanuel, lati ijọ Living Spring International sọ fun BBC pe, igbeṣẹ awọn Kristẹni lati ṣe iwode jẹ igbesẹ to dara.

Oríṣun àwòrán, Femi Emmanuel

Bo tilẹ jẹ pe o ni iwọde naa ko le sọ ijọba to wa lode yii ji, o ni akitiyan awọn kristẹni ku diẹ kaato lori ọrọ oṣelu lorilẹ-ede yii.

O ni ko yẹ ki awọn ọmọlẹyin Kristi ati awon olori ijọ bii baba Adeboye fọwọ lẹran lori ohun to n lọ ni Naijiria.

Àkọlé fídíò,

Human trafficking: Iṣẹ́ irun ṣíṣe ló di iṣẹ́ aṣẹ́wó

Pasitọ ọhun ni iṣoro kan gboogi to n ba Naijira finra ni iṣoro olori, nitori naa, awọn kristẹni ni lati darapọ mọ oṣelu lọna ati yan olori rere fun orilẹ-ee yii.

O ṣalaye siwaju sii pe adura nikan ko to, ṣugbọn ijọ ni lati ji giri si ojuṣe wọn nipa kikopa ninu eto oṣelu.

Ọjọ Keji Osu Keji ọdun 2020 ni awọn Kritẹni kan ṣewọde lodi si bi nnkan ṣe n lọ ni ẹka eto aabo ati bi awọn ẹgbẹ agbesumọmi Boko Haram ṣe n pa awọn Kristẹni lorilẹ-ede yii, eyii ti alufa agba ijọ Irapada, E.A. Adeboye dari rẹ.

Àkọlé fídíò,

'Ọwọ́ tó bá dilẹ̀ ni èṣù ń bl ní iṣẹ́kíṣẹ́'