Muslim Marriage: Lẹ́yin ìsopọ̀ ogún ọdún, ìyàwò fẹ́ ṣèyàwó lábẹ́ òfin

Tọkọ-tiyawo to n kirun Image copyright Getty Images

Ileejọ kan ti fagile igbeyawo nilana ẹsin Musulumi lẹyin to da idajọ ileẹjọ kan nu, eyi to fontẹ lu pe, igbeyawo nilana ẹsin Islam ba ofin mu ni ilu Ọba, United Kingdom.

Mohammed ati Nasreem se igbeyawo nilu London lọdun 1998 niwaju Imaamu ati awọn ẹlẹri aadọjọ, ti ọba oke si fi ọmọ mẹrin si aarin wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ lati ọdun 2018, eyiun ọdun meji sẹyin ni Nasreen ti n wọna nile ẹjọ lati da igbeyawo naa nu.

Nasreen ni ko si igbeyawo laarin oun ati Muhammed niwọn igba ti ko ti lọwọ ofin ninu, saaju si ni aawọ ti wa laarin tọkọtaya naa, eyi to mu ki wọn maa gbe lọtọọtọ lati ọdun 2016.

Image copyright Getty Images

Igbẹjọ to kọkọ waye saaju si ti kede pe igbeyawo nilana ẹsin Islam wa laarin awọn mejeeji, to si ba ofin igbeyawo ilẹ Gẹẹsi mu.

Sugbọn Nasreen morile ileẹjọ Kotẹmilọrun lori ọrọ yii, amọ ti ileẹjọ naa da ẹjọ ọhun nu lọdun 2018, to si kede pe igbeyawo to waye laarin Mohammed ati Nasreen ko bofin mu.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionStray Bullet: Bàbá ọmọ ni ogún náírà péré ni àwọn ọlọ́pàá fi lọ òun àmọ́ òun kò gbàá

Amọ lẹyin tile ẹjọ kede idajọ rẹ tan, to si da igbeyawo nilana ẹsin islam naa nu laarin Nasreen ati Mohammed, ni Nasreen ba n lakaka pe ki awọn tun igbeyawo awọn se nilana ofin orilẹede Gẹẹsi.