Ọmọ Uganda tó kópa nínú fíímù Queen of Katwe, Nikita Pearl Waligwa ti ku

Nikita Pearl Waligwa kopa Gloria, ọrẹ Phiona, to kọ ọ bi wọn ṣe n ta ayo 'chess' Image copyright disney
Àkọlé àwòrán Nikita Pearl Waligwa kopa Gloria, ọrẹ Phiona, to kọ ọ bi wọn ṣe n ta ayo 'chess'

Oṣerebinrin tọjọ ori rẹ kere ju, to kopa ninu ere 'Queen of Katwe' - fiimu Disney kan nipa ọmọde to le ta ayo Chess daada botilẹjẹ pe inu iṣẹ ati oṣi lo ti dagba ni Uganda ti ku lọmọ ọdun mẹẹdogun.

Gẹgẹ bi awọn akọroyin ni Uganda ṣe sọ, wọn ni jẹjẹrẹ inu ọpọlọ ni ọmọ naa, Nikita Pearl Waligwa ni.

Fiimu to ṣe lọdun 2016 jẹ itan igbe-aye Phiona Mutesi, to bẹrẹ si ni ta ayo Chess lọmọ ọdun mẹsan, bo tilẹ jẹ pe ko lọ sileewe rara, ṣugbọn o gbe ayo naa de ipele to lagbara, to si bẹrẹ si ni kopa ninu idije agbaye.

Awọn oṣere bii Lupita Nyong'o to ṣe iya rẹ, ati David Oyelowo, to ṣe olukọ to kọ bi wọn ṣe n ta ayo 'Chess, lo kopa ninu fiimu naa.

Waligwa kopa bi i Gloria, ọrẹ Phiona to ṣalaye bi wọn ṣe n ta ayo naa fun.

Ọdun 2016 ni wọn ti kọkọ sọ nileewosan pe o ni jẹjẹrẹ inu ọpọlọ.

Iroyin si sọ pe oludari fiimu 'Queen of Katwe, Mira Nair, ko awọn eniyan jọ lati da owo ti wọn yoo fi ṣe iṣẹ abẹ fun ni India, 'nitori pe awọn dokita Uganda sọ pe awọn ko ni irinṣẹ lati tọju rẹ'.

Botilẹjẹ pe wọn sọ l'ọdun 2017 pe ara rẹ ti n ya, wọn pada ri jẹjẹrẹ miran l'ọdun to kọja.