Ẹbí ìyàwó lu ọkọ ìyàwó lẹ́yìn tí ìyàwó rẹ̀ yọjú síbi ìgbéyàwó tó ṣe pẹ̀lú obìnrin mìràn

Awọn ẹbí iyawo tuntun fi iya nla jẹ Asif Rafiq Siddiqi. Image copyright Social media
Àkọlé àwòrán Awọn ẹbí iyawo tuntun fi iya nla jẹ Asif Rafiq Siddiqi.

Nise ni awọn eero le ọkọ iyawo kan kabakaba kuro ni ibi ayẹyẹ igbeyawo rẹ lẹyin ti iyawo rẹ akọkọ ṣadeede yọju sibi ayẹyẹ naa, to si sọ fun iyawo tuntun pe, ọkọ rẹ ti ni iyawo meji tẹlẹ.

Awọn eero naa fa aṣọ Asif Rafiq Siddiqi ya, wọn gba a ni ẹṣẹ, wọn gba a leti, wọn si tun gba ṣokoto nidi rẹ lẹyin ti wọn gbọ pe o ti gbeyawo tẹlẹ.

Botilẹjẹ pe ofin orilẹ-ede Pakistan faaye gba iyawo pupọ, ti ọkunrin si le fẹ to iyawo mẹẹrrin, awsn iyawo ti iru ọkunrin naa ti kọkọ fẹ gbọdọ fi ọwọ si ko to o le gẹ omiran.

O dabi ẹni pe ọgbẹni Siddiqi ko sọ fun awọn iyawo rẹ pe oun fẹ ẹ fẹ ẹlomiran le wọn, awọn ẹbi iyawo tuntun ko si mọ pe ọkọ ọmọ wọn ti ni iyawo miran titi di igba ti iyawo rẹ akọkọ tu aṣiri nibi ayẹyẹ igbeyawo to waye nilu Karachi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOmi titun ti rú nínú oríṣii ètò ìgbéyàwó Yorùbá lásìkò yí

Fidio kan nipa iṣẹlẹ naa fihan bi ọkan lara ẹbi iyawo tuntun ṣe n beere lọwọ obinrin naa pe 'sista, ki lo ṣẹlẹ, ki lẹ fẹ'?

Obinrin naa, Madiha Siddiqi ko si fi akoko ṣere rara to fi dahun pe ọkọ mi niyẹn.

"Ọkọ mi ni, oun si ni baba ọmọ ti mo mu dani yii. Ilu Hyderabad lo da gbere fun mi pe oun ma wa fun ọjọ mẹta."

Image copyright others
Àkọlé àwòrán Obinrin kan to sọ pe oun ni iyawo Asif da ayẹyẹ igbeyawo naa ru.

Awọn ẹbi naa gbiyanju lati mu u wọ inu yara kan ni kọọrọ, eyi to fun ni anfaani lati nawọ si awọn to pe ni ẹbi rẹ.

Arabinrin Siddiqi sọ pe "Mama ọkọ mi niyẹn, aburo ọkọ mi kan naa dẹ tun niyẹn", ko to o ksju si iyawo tuntun pe:

"Ṣe o ko mọ pe ọkọ mi ni? Ko ti ẹ ro ti ọmọ ẹ ti ko ni ẹṣẹ lọrun rara."

Aburo ọkọ naa lo sọ pe bi ọjọ mẹta ni iya awọn ti n ṣaarẹ, ti wọn si n fa omi si lara.

Ọrọ ko tan sibẹ o. Arabinrin Siddiqi sọ pe ọdun 2016 ni oun fẹ ọkunrin naa, lẹyin ti awọn pade ni ileewe Federal Urdu University, nilu Karachi, nibi ti Ọgbẹni Siddiqi ti n ṣiṣẹ.

Arabinrin Siddiqi sọ pe ọkọ oun ko kọkọ jẹwọ pe o ti ni iyawo tẹlẹ, ko to o pada sọ pe oun ti fẹyawo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionNo reception wedding: Adewale ni àpèjẹ kò ṣe pàtàkì sí òun

A ko fibẹ mọ nkan to pada ṣẹlẹ, ṣugbọn ileeṣẹ ọlọpaa ti wọn kesi lati wa yanju ọrọ sọ fun BBC pe mọlẹbi iyawo tuntun naa yabo Asif, wọn ya aṣọ rẹ, wọn si tun lu u bi aṣọ ofi.

Awọn ọlọpaa lo gba Asif silẹ, ti wọn si mu lọ si agọ ọlọpaa to wa nitosi ibi ti ọrọ ti waye - ṣugbọn awọn ẹbi iyawo ma tun tẹle wọn debẹ lati gbẹsan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIle ejo kan ti so ni odun to koja pe ijoba ipinle ati ibile ko le se igbeyawo

Ni kete ti Ọgbẹni Siddiqi si yọju sita ni wọn kọlu u - wọn ju u si abẹ ọkọ bọọsi kan.

Ninu fidio kan to ṣe afihan rẹ, a gbọ ohun to n dẹruba a pe "jade wa tabi ka dana sun bọọsi yii."

BBC gbiyanju lati ba Ọgbẹni Siddiqi ati iyawo rẹ tuntun sọrọ lori iṣẹlẹ naa, ṣugbọn wọn ko si ni arọwọto.

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí