Mother Language Day: Bàbá míì ní àìkọ́ ọmọ òun ní Yorùbá ló mú kò pàdánù iṣẹ́ olówó ńlá

Mother Language Day: Bàbá míì ní àìkọ́ ọmọ òun ní Yorùbá ló mú kò pàdánù iṣẹ́ olówó ńlá

Yoruba ni ko sibi to dabi ile ni ẹyẹ n ke, ko si ibi to dabi ilu taa bi ni, bẹẹ si ni ọmọ to sọ ile nu, ti so apo iya kọ.

Lonii ayajọ ọjọ agbelarugẹ ede abinibi ẹbi lagbaye, awọn obi kan ti n sọ iriri wọn lori ka kọ ọmọ lede abinibi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bi baba kan se n yangan pe oun n kọ awọn ọmọkunrin oun mẹtẹẹta , ti iyawo rẹ oyinbo bi fun, ni ede abinibi lai naani pe awọn n gbe loke okun, naa ni baba miran to n gbe lorilẹede Naijiria n ge ika jẹ pe oun ko fi ede abinibi kọ ọmọ oun.

Eyi lo ni o jẹ ko padanu isẹ olowo nla to yẹ ko ri gba lẹyin to jade nileẹkọ.

Fidio yii kọ ni lẹkọ pupọ, ẹ gbọ ọrọ lẹnu awọn to n poungbẹ agbelarugẹ asa, kẹ si kọgbọn.