Sex for Marks: Aago 9.25 àárọ̀ ni olùkọ́ fi tipá bá akẹ́kọ̀ọ́ náà lòpọ̀ nínú ọọ́fìsì

Obinrin kan ninu okunkun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Yoruba ni ẹni to ba mọ isin jẹ, o yẹ ko mọ ipin oju rẹ yọ nitori ohun ti eeyan ba mọ jẹ, nii yo.

Bẹẹ lọrọ ri fun olukọ kan tẹlẹ ni fasiti Eko, Azeez Baruwa, tileeẹjọ giga Eko ni ko yara lọ na naju lọgba ẹwọn fun ọdun mọkanlelogun.

Ẹsun ti wọn fi kan Baruwa ni pe o fi tipa tikuuku ba ọmọbinrin kan, ẹni ọdun mejidinlogun lopọ, ẹni to n wọna bi yoo se wọle sinu ọgba ileeẹkọ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Akẹkọ naa la gbọ pe o gba maaki okoolerugba o din mẹsan ninu idanwo asewọle sile ẹkọ naa , to si fẹ kọ nipa isẹ ibaraẹnisọrọ, Mass Communication.

Amọ riro ni ti eniyan, sise ni ti Ọlọrun, lẹyin ti ọmọ yii kuna lati ni maaki tileẹkọ naa n beere fun lori imọ isẹ to fẹ se, ni baba ọmọdebinrin naa ba tọ Baruwa lọ.

Oríṣun àwòrán, Others

Baruwa, to n fi isẹ olukọ se idabọ ni ẹka imọ nipa isiro owo lo si gba lati seranwọ fun baba naa, to si gbe ọmọ ọhun ls sile ẹkọ fasiti naa lọjọ kẹtalelogun osu keje ọdun 2015.

Amọ ẹni ti a gboju okun le, ti ko jọ ẹni agba ni olukọ naa, tori o fi tipa ba ọmọdebinrin naa lopọ ni aago mẹsan kọja isẹju mẹẹdọgbọn aarọ ni yara kẹjọ to wa ni ọọfisi ẹkọ nipa isẹ okoowo.

Oríṣun àwòrán, Others

Ọmọbinrin naa ko fi isẹlẹ yii se osun, ko fi kinra, amọ o dele, o sọ fun awọn obi rẹ, ti ọrọ naa si de etigbọ ẹgbẹ ajafẹtọ ẹni kan, to gba ẹjọ ọhun kanri.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ lori ẹsun naa, Adajọ Josephine Oyefẹsọ ni afurasi naa mọ bi ọran to da se lowura to, ati bi ijiya rẹ se gbopọn si, nitori oun lo fi tipa jabale ọmọ naa.

Àkọlé fídíò,

Mother Language Day: Bàbá míì ní àìkọ́ ọmọ òun ní Yorùbá ló mú kò pàdánù iṣẹ́ olówó ńlá

O ni ọgbẹ ọkan nla ti yoo wa titi aye ni isẹlẹ naa jẹ fun ọmọbinrin ọhun, eyi toun n gbadura pe ko san.

Lẹyin eyi lo wa ni ko lọ fi asọ penpe roko ọba fun ọdun mọkanlelogun gbako.