Coronavirus: Àwọn olúlùfẹ́ fí ìbòjú fi ẹnu ko ara wọn ní Philippine

Coronavirus: Àwọn olúlùfẹ́ fí ìbòjú fi ẹnu ko ara wọn ní Philippine
Ijọba orilẹede naa pese ayẹwo bi ara ṣe gbona si ati ohun ibo ẹnu lati le dẹkun itankalẹ arun coronavirus.

Oríṣun àwòrán, BACOLOD PUBLIC INFORMATION OFFICE

Àkọlé àwòrán,

Ijọba orilẹede naa pese ayẹwo bi ara ṣe gbona si ati ohun ibo ẹnu lati le dẹkun itankalẹ arun coronavirus.

Igbeyawo ọlọgọ̀ọrọ to n waye ni orilẹede Philipine gba ọna miran yọ lọdun yii latari arun coronavirus to sọsẹ lorilẹede naa.

Fidio ṣe afihan ẹgbẹgbẹrun awọn ololufẹ to fi iboju bo ẹnu wọn lati fi ẹnu ko ẹnu.

Bakan naa ni wọn ṣe ayẹwo ara wọn lẹyọ kọọkan ki wọn to wọ gbagede ti wọn ti ṣe iyawo naa.

Ọna ati dena itankalẹ arun naa ni wọn ṣe ṣe bẹẹ ni ọdun yii.

Lorilẹẹede Philipine, ọdọọdun ni ijọba ma n ṣe iranwo fun awọn ọgọọrọ ololufẹ ti wọn ba ṣetan lati fẹ ara wọn bii tọkọtaya.

Arun Coronavirus to bẹrẹ ni orilẹede China, ti tan kaakiri agbaye to fi mọ ilẹ Afirika, amọ ko i ti de orilẹede Naijiria.

Ọpọlọpọ ẹmi losi ti ba iṣẹlẹ naa lọ, koda orilẹede Italy tilẹ ti awọn ile iwe, ti wọn fi gbegile ere idaraya to yẹ ko waye lorilẹede naa.

Bẹẹ si ni ọpọlọpọ ilu lo wa ni atimole, ti wọn ko jẹ ki wọn rin lati ilu kan si omiran, lọna ati dẹkun itakanlẹ arun corona virus naa.