Coronavirus: Oṣù kan gbáko lèèyàn 16 mílíọ̀nù yóò fi wà lábẹ́ ìséde ni Italy

Aworan awọon ọlọpaa ati ọmọ ogun to ṣetan lati fi ofin konileogbele rinlẹ

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Awọn ọlọpaa ati ọmọ ogun tṣetan lati ti ilu Milan pa

Minisita feto ilera orileede Italy sọ pe o keere tan eeyan miliọnu mẹrindinlogun lofin konileogbele yoo kan ni agbegbe Lombardy ati awọn ileto mẹrinla miran f'osu kan gbako.

Igbesẹ yi gẹgẹ bi wọn ṣe sọ jẹ ọna kan gbogi lati koju aisan Coronavirus to n ja rain nilẹ naa.

Lara eto yi lo sọ pe awọn yoo ti sọ agadagodo pa si awọn ibudo ere idaraya to fi mọ ibudo iko nkan iṣẹmbaye lariwa orileede naa.

Ayẹyẹ igbeyawo ati isinku naa ko ni waye lasiko idejumọle yi.

Orileede Italy ni aisan Coronavirus ti gbogo julọ ni ilẹ Yuroopu.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ilana tuntun ti wọn kede yi yoo kan ilu Milan ati awọn ibudo igbafẹ miran ni Venice ti yoo si kan wọn titi di ọjọ kẹta oṣu Kẹrin.

Awọn to ti padanu ẹmi wọn lọwọ aisan naa ni Italy bayi ti kọja okoolenigba ati mẹwa(230) tawọn alaṣẹ si n kede iku eeyan aadọta laarin wakati mẹrinlelogun.

Bẹẹ si ni iye eeyan to ko aisan naa ti fo lati ẹgbẹfa(1200) si ẹgbẹrun marun un ati ọọrinlelẹgbẹrin ati mẹta(5883) lọjọ Abamẹta.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Onikaluku ti n yara ra ounjẹ sile de ibẹrẹ ofin konileogbele

Minisista Guiseppe Conte sọ pe ''a fẹ daabo bo ẹmi awọn ọmọ ilẹ wa.A mọ pe awọn igbes yi yoo gba ka ṣe ifarada kekeeke ati awọn mi ti yoo ga''

''Ṣugbọn o di dandan, a ni lati gba akoso itọju ara wa''

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán,

Wọn n fin awọnile ijọsin ni Naples lọna ti koju Coronavirus

Yatọ si awọn to wa ni ariwa agbegbe Lombardy, awọn to wa ni Modena, Parma, Piacenza, Reggio Emilia, Rimini, Pesaro ati Urbino, Alessandria, Asti, Novara, Verbano Cusio Ossola, Vercelli, Padua, Treviso ati Venice lọrọ yi kan.

Ṣaaju asiko yi eeyan ẹgbẹrun lọna aadọta ni wọn ti ya sọtọ ti wọn fura si wọn pe wọn le ni aisan naa ni ariwa Italy.