Coronavirus symptoms: Kí ni àwọn àpẹẹrẹ àrùn yìí, àti pé báwo ni mo ṣe leè dáàbò bo ara mi?

Coronavirus

Arun Coronavirus ti tan de, o kere tan, ọgọrin orilẹ-ede, ilẹ Gẹẹsi ati Naijira si jẹ ọkan lara rẹ.

Ṣugbọn kinni arun yii, ati pe bawo ni o ṣe n tan ka?

Bawo ni mo ṣe lee dabo bo ara mi?

Ọna to dara ju lati dabo bo ara ẹni ni lati maa fọ ọwọ ẹni, paapa pẹlu omi ati ọṣẹ.

Arun Coronavirus ma n tan kan nigba ti ẹni to ba ti lugbadi arun naa ba wukọ, ti afẹfẹ si gbe. Ẹlomiran le mi iru afẹfẹ bẹ simu, tabi to ba fọwọ kan ibi (ori aga ijoko tabi ori tabili) ti arun naa ti bale, ti iru ẹni bẹ si fi ọwọ naa si oju, imu tabi ẹnu rẹ.

Nitori naa, ki eeyan wukọ tabi sin sinu igbọnwọ, ṣiṣọra fun fifi ọwọ ti eeyan ko fọ kan oju ẹni, ati yiyẹba fun awọn to ni ti ni arun naa jẹ ọna kan pataki lati jina rere si arun ọhun.

Awọn onimọ eto ilkera ti sọ pe Lilo iboju ko le fun eeyan ni abo to koju oṣuwọn lori arun naa.

Ki ni awọn apẹrẹ arun Coronavirus?

Ẹdọforo ẹni ni aruin Coronavirus ma n kọ lu, apẹrẹ arun ọhun si ma n bẹrẹ pẹlu iba, lẹyin rẹ ni ikọ, leyi to le yọri si isọro ati mi.

Gẹgẹ bi awọn onimọ ijinlẹ ṣe sọ, apẹrẹ arun le bẹrẹ lati ẹyin ọjọ marun un ti eeyan ba ti lugbadi rẹ.

Awọn to ba ti n fi apẹrẹ arun naa han lee ko ran elomiran ṣugbọn awọn ami kan ti fi han pe, awọn to ni arun ọhun le ko ran elomiran lai ṣe pe wọn ti bẹrẹ si n fi apẹrẹ rẹ han.

Apẹrẹ arun ọhun le fara jọ aisan to wọn pọ bi otutu ati ọfinki, leyi to le ma mu ki eeyan tete fura pe Coronavirus lo n ba oun ja.

Bawo ni arun Coronavirus ṣe buru to?

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionLàá hàn mí: Ètò yìí ló ń kìlọ̀ fún wa láti mú ìmọ́tótó ní pàtàkì láti dènà Coronavirus

Lọwọ yii, o jọ bi pe awọn to n jẹ Ọlọrun nipe nipasẹ arun naa kere jọjọ, bi ida kan si meji ninu ida ọgọrun.

Ẹgbẹgbẹrun eeyan ni wọn ti n gba itọju lọwọ, ṣugbọn o ṣeṣe ki awọn naa jẹ Ọlọrun nipe, to tunọ si pe iye awọn to gbẹmi mi nitori arun naa le ga ju iwọn to wa nilẹ lọ, bakan naa, iye eeyan naa tun le lọ silẹ ju bi awọn onimọ ṣe lero lọ.

Iwaadi ti ajọ eleto ilera agabye. WHO ṣe lara awọn eeyan ẹgbẹrundinlọgọta fi han pe:

  • 6% ṣaisan naa gidi -ẹdọforo wọn kọṣẹ, ẹya ara wọn kan ko ṣẹṣẹ daadaa leyi to le yọri si iku.
  • 14% fi apẹrẹ arun naa han - o si ṣoro fun wọn lati mi.
  • 80% wọn fi apẹrẹ diẹ han - wọn ni iba ati ikọ.

Awọn agbalagba ati awọn ti wọn ti ni aisan lara tẹlẹ (bii itọ ṣuga, aisan inu ọkan ati ikọ efee) le ṣaisan gidi.

Itọju iru awọn bẹẹ si da le jijẹ ki wọn wa laaye titi ti ohun amuṣagbara ninu agọ ara wọn le fi le arun naa lọ. Ṣugbọn awọn eleto ilera ti n ṣeṣẹ lati ri ogun to le koju arun naa.

Kinni mo le ṣe ti mo ba ni arun Coronavirus?

Ajọ NHS ti sọ pe o ṣeṣe ki arun yii gbilẹ siwaju si nilẹ Gẹẹsi.

Awọn ti wọn ba ni arun naa ni UK le pe ago NHS lori nọmba 111 fun igbani niyanju.

Awọn to wa ni Naijiria ti wọn ba ri pe wọn ti ṣalabapade ẹni to ni arun ọhun lee pe nọmba 0800-970000-10 tabi 112.

Oriṣiriṣi orilẹ-ede lo ti fi amọran lede fun awọn eeyan wọn lori awọn ohun ti wọn le ṣẹ ti wọn ba lugbadi arun naa tabi fara kan ẹni ti wọn funra si pe o ni arun ọhun.

Bawo ni mom ṣe le ṣayẹwo arun naa?

Ti o ba wa ni ilẹ Gẹẹsi ti o si nilo ayẹwo, mu diẹ lara itọ, igbẹ tabi ẹjẹ rẹ lọ sile iwosan fun ayẹwo naa.

Ti o ba duro de esi ayẹwo rẹ, o dara ki o da wa ninu ile titi ti esi ayẹwo naa yoo fi de.

Igbesẹ kan naa lo ni lati gbe to ba wa ni orilẹ-ede Naijiria.

Bawo ni arun yii ṣe n tan kaakiri?

Ọpọ awọn eeyan lo n fara kaasa arun yii kaakiri agabye, ṣugbọn ọpọ awọn mii to n ko arun naa ni awọn eleto ilera ko mọ nitori wọn ko fi to wọn leti.

Lẹyin to bẹrẹ ni China, arun naa ti tan de South Korea, Italy, Iran atawọn ilẹ mii lagabye.