Coronavirus: Àjọ elétò ìlera lágbàyé tí pe Coronavirus ní àjàkálẹ̀ àrùn káàkiri àgbáyé

Coronavirus Image copyright Getty Images

Ajọ eleto ilera ni Agbaye, WHO ti pe arun Coronavirus ni ajakalẹ arun to n ja kaakiri agbaye.

Alaga ajọ WHO, Dokita Tedros Adhanom Ghebreyesus ni iye awọn eniyan to ti lugbadi awọn arun naa ni awọn orilẹede miran yatọ si China ti peleke si ni ida mẹtala laarin ọsẹ meji.

Tedros Adhanom Ghebreyesus ni oun ṣe oun laanu pe awọn eniyan ko i tii kọ ibi ara si ajakalẹ arun naa

Image copyright EPA

.

Ajakalẹ aarun tun mọ si pe arun naa n kaakiri orilẹede pupọ ni ẹẹkan naa.

Amọ Tedros Adhanom Ghebreyesus ni pipe arun naa ni ajakalẹ aarun ko tu mọ si pe ko ni si ọna abayọ lati kapa aarun naa.

Eré bọ́ọ̀lù, ìpàdé ìta gbangba àtàwọn nǹkan míì tó di àpatì torí Coronavirus

Lati igba ti arun Coronavirus ti bẹ silẹ ni ilu Wuhan, lorilẹ-ede China lọdun 2019, ọpọloọpọ awọn eeyan lo ti lugbadi arun naa kaakiri agbaye.

Bi arun naa ṣe n da ẹmi awọn eeyan legbodo na lo n fa idaduro si oriṣiriṣi awọn ayẹye, eto, ipade, ere idaraya atawọn nkan mii to yẹ ko waye.

Iwọnyi ni awọn ohun to yẹ ko waye, ṣugbọn ti awọn ti ọrọ kan gbegile, tabi ṣe atunto rẹ nitori arun ọhun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionLàá hàn mí: Ètò yìí ló ń kìlọ̀ fún wa láti mú ìmọ́tótó ní pàtàkì láti dènà Coronavirus

Ere idaraya

Ọpọ ifẹṣewọnsẹ ere bọọlu ajọ Yuroopu, EPL, to yẹ ko waye ni wọn ti wọgile laipẹ yii, ti awọn alaboju ifẹsẹwọnsẹ naa pinnu pe ki diẹ lara ifẹsẹwọnsẹ naa waye lai si ero iworan.

Fun apẹrẹ, wọn sun ifẹsẹwọnsẹ laarin ikọ Arsenal ati Manchester City to yẹ ko waye lọjọ kọkanla Oṣu Kẹta ọdun yii siwaju.

Ni orillẹ-ede Italy, awọn alakoso ere bọọlu nibẹ, Italian Football Federation (FIGC) sọ lẹyin ipade kan pe, o ṣeṣe ki idije Serie A saa yii ma pari nitori arun naa.

Ko tan sibẹ, ajọ to n ri si ere bọọlu lagbaye, FIFA sọ pe, o ṣeṣe ko sun awọn igbaradi fun idije bọọlu agabye, Qatar 2022 siwaju.

Ni ti idije Olimpiiki to yẹ ko bẹrẹ loṣu keje ọdun 2020, awọn igbimọ to n risi eto na ti ni kaka ki wọn wọgile, niṣe ni wọn yoo jẹ ko waye laisi ero iworan, ṣugbọn ko ṣeni to mọ ohun ti le ṣelẹ.

Image copyright @habsonfloww

Eto aṣa

Laarin ọsẹ yii ni ijọba Yuroopu wọgile gbogbo ohun to jẹ mọ ipade ita gbangba lati le dẹkun itankalẹ arun naa, koda, wọn gbẹsẹ le lilọ si ile ijọsin.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionStolen phone: Fóònù mi ni mo lọ́ tún ṣe lọlọ́pàá bá he mí pé mo jí fóònù

Lọjọ Aje, ọjọ kẹsan an oṣu yii ni ijọba Ireland wọgile iwọde ayajọ ọjọ St. Patrick to waye ni Dublin.

Ọpọ ibi ni Germany, paapaa ni Berlin ni wọn ti wọgile awọn ohun to le mu ki awọn eeyan korajọ pọ soju kan naa, bi ile iworan tiata, ati bẹbẹ lọ.

Image copyright Getty Images

Afihan ọkọ ayọkẹle ita gbangba to yẹ ko waye ni New York, lorilẹ-ede Amẹrika lọṣu Kẹrin ọdun 2020 naa ni wọn tun ti sun siwaju.

Ipade oṣelu

Nilẹ Amẹrika, Sẹnatọ Bernie Sanders ati igbakeji aarẹ tẹlẹ, Jospeh Biden naa sun ipolongo idibo sipo aarẹ to yẹ ko waye lọjọ Kẹwa Oṣu Kẹta ọdun yii ni Ohio siwaju latari ibẹru arun Coronavirus.

Ipade ajọ banki agabye

Ipade ajọ banki agabye ọlọdọdun to yẹ ko waye ni Washington ni wọn ti ṣatunto rẹ bayii.

Awọn ti ọrọ kan ti wa wọrọko fi ṣada ni bi wọn ṣe gbe igbesẹ lati ṣe ipade naa lori itakun agbaye dipo ki wọn ṣe loju koju.

Irinajo si Saudi Arabia

Awọn ẹlesin Musulumi ti wọn ti n gbaradi lati goke Arafa lọdun yii ko le ni anfani ati ṣe bẹ nitori ọwọja arun Coronavirus yii kan naa.

Laipẹ yii ni ijọba Saudi kede pe, wọn gbẹsẹle gbogbo irinajo okere si orilẹ-ede wọn fun igba diẹ titi ti arun ọhun yoo fi kasẹ nile.

Ere agbelewo

Fiimu James Bond kan ti awọn olotu rẹ lero pe yoo waye loṣu Kẹrin ọdun yii ni wọn ti sun siwaju. Sinima naa ti akọle rẹ n jẹ "No time to Die" ni wọn sun si Oṣu Kọkanla ọdun 2020 dipo Oṣu Kẹrin.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFacebook love: Ọla àti Folashade ṣègbéyàwó lẹ́yìn ọjọ́ mọ́kànlá tí wọ́n ríra ni Facebook