Coronavirus: Gbogbo igbá ti ṣófo láwọn ilé ìtajà káàkiri London

Coronavirus: Gbogbo igbá ti ṣófo láwọn ilé ìtajà káàkiri London

Iku tó n gbojugba ẹni....

Oladimeji Solomon, ọmọ Naijiria to fi London ṣe ibujoko ni United Kingdom ba BBC sọrọ lori ipa ti ofin konile-o-gbele to ṣẹlẹ ni UK ni bayi.

Ọpọ awọn ero lo n sare lọ ra ohun jijẹ ati ohun eelo ile ni awọn ile itaja nla nla.

Ninu ibẹrubojo ni awọn eeyan n lọ ko nkan sile ti ọpọ ọja si ti tan lori igba nile itaja bayii.

Solomon Oladimeji soro ni kikun lori ipa ti ofin yii le ni lori ọrọ aje ati igbe aye awọn eniyan lasiko ibẹru coronavirus yii.