Coronavirus in Nigeria: Báyi ni ẹ ṣe leè ṣe "hand sanitizer" nínú ilé yín

Coronavirus in Nigeria: Báyi ni ẹ ṣe leè ṣe "hand sanitizer" nínú ilé yín

Lati igba ti arun Coroavirus ti bẹ silẹ lorilẹ-ede China lọdun 2019, arun naa ti rapala wọ ọpọlọpọ orilẹ-ede l’gbaye, ti ilẹ Naijiria ko si gbẹyin.

Lẹyin ti arun naa wọ ilẹ Naijiria tan ni awọn nkan ti eeyan le fi daabo bo ara rẹ bi ibomu pẹlu hand sanitizer ti di ọwọn gogo.

Lai si aniani, eeyan nilo hand sanitizer lati le jẹ ki ọwọ rẹ wa ni imọtoto nitori ohun ipawọ ọhun lagbara lati pa awọn kokoro aifojuri.

Fidio yii kọni bi eeyan ṣe le ṣe hand sanitizer ninu ile ara rẹ pẹlu owo perete.

Awọn ohun ti eeyan nilo ni ethanol tabi Isopropyl, methylated spirit, ewe aloe vera, ati lọfinda.

Ti ẹ ba ti po gbogbo ẹ papọ gẹgẹ bi o ṣe wa ninu fidio yi, iṣẹ ti bẹrẹ niyẹn.