Farhiya Sharif: Inú dígí ni mò ń wò nígbà tí mo bá fẹ́ mọ bàbá mi

Farhiya ati baba rẹ

Oríṣun àwòrán, Farhiya

Obinrin ẹni ọdun mọkandinlogoji kan ti ṣawari baba rẹ to ti n wa lati igba ti wọn ti bii pẹlu iranlọwọ ikanni Facebook lori ayelujara.

Wọn bi Farhiya ni Lenigrad, to ti yi orukọ da si St Petersburg lọdun 1976, iya rẹ jẹ ọmọ orilẹ-ede Rusia, nigba ti baba rẹ jẹ ọmọ ilẹ Somalia.

Baba rẹ, Siid Ahmed Sharif jẹ ọkan lara awọn ologun to lọ kọ ẹkọ labẹ iṣejọba Soviet Union lọdun naa lọhun, ṣugbọn lẹyin ọdun kan ti wọn bi obinrin naa, ija bẹ silẹ laarin orilẹ-ede Ethiopia ati Somalia.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ijọba USSR ṣegbe lẹyin Ethiopia ninu ogun naa, eyii to mu ko le awọn ọmọ ilẹ Somalia to n kọ ẹkọ labẹ rẹ pada sile, lara awọn ti wọn le pada sile ni baba obinrin ọhun wa.

Farhiya ni gbogbo igba ti oun ba n beere bi baba oun ṣe ri lọwọ iya oun, ni ṣe lo maa n sọ fun oun pe, ki oun wo inu digi pe oun yoo ri baba oun nibẹ.

Oríṣun àwòrán, Farhiya

Lẹyin nnkan bi ogoji ọdun to ti n ṣafẹri baba rẹ, Farhiya kan si oju opo ikansiraẹni lori itakun agbaye kan, Vkontakte, ti wọn ti maa n ṣawari awọn ti wọn ko mọ ẹbi wọn, ṣugbọn pabo lo ja si.

Lẹyin o rẹyin, Farhiya pade ọkunrin kan ti wọn n pe Deeq, eyii to fi ẹbẹ Farhiya soju opo Facebook rẹ, awọn eeyan si bẹrẹ si n da si ọrọ naa.

Bi ere bi awada, ẹnikan lati Norway to jẹ ẹbi baba rẹ da si ọrọ ọhun.

Koda, ọdọ ẹni naa ni baba Farhiya n gbe ni ilu Oslo lasikọ to da si ọrọ naa lori Facebook.

Oríṣun àwòrán, Farhiya Sharif

Lẹyin ọsẹ diẹ si, Farhiya ati baba rẹ fojurinju lori ẹrọ Skype ti wọn si sọrọ, ko pẹ si akoko naa ti oun, iya rẹ ati ọkọ tẹkọ leti lọ si Norway lati pade baba rẹ lẹyin nnkan bi ogoji ọdun.

Farhiya sọ fun BBC lẹyin to pade baba rẹ tan pe "bi mo ṣe lero pe baba mi yoo ri gan lo ri."

"Bakan ni a ṣ e n rin, bakan naa ni a ṣe n sọrọ, o jẹ ohun to yamilẹnu pupọ."