Ìgbìmọ̀ aláàṣẹ Nàìjíríà ti buwọ́lu ọjọ́ orí ìfẹ̀yìntì tuntun fún àwọn olùkọ́

Tisa

Oríṣun àwòrán, Google

Igbimọ alasẹ orilẹ-ede Naijiria ti fi ọwọ si aba ofin tuntun ti isejọba to wa lori oye lọwọ lọwọ fẹ ẹ ma lo lati mu idagbasoke ba isẹ olukọ ni Naijiria.

Lara ohun to wa ninu ofin naa ni àbá ofin to ni i ṣe pẹlu ọjọ ori ti awọn olukọ yoo ma a fẹhinti.

Wọn si ti fi aba naa ránṣẹ si ile aṣofin fun agbeyẹwo ati àṣẹ ti yoo sun ọjọ ori ífẹhinti awọn olukọ kuro ni ọgọta ọdun si ọdun marunfinlaadọrin.

Bakan naa ni wọn fẹ ki iye ọdun ti wọn fi n sisẹ yipada kuro ni ọdun marundinlogoji si ogójì ọdun.

Àkọlé fídíò,

Akomolede ati Asa: Alagba Ajibola láti Fakunle ní olùkọ́ wa lórí ètò ìró lónìí

Minisita fun eto ẹ̀kọ́, Mallam Adamu Adamu lo sọ ọrọ naa fun awọn akọroyin nile ijọba Aso Rock, lopin ipade akọkọ ti Aarẹ Muhammadu Buhari dari.

Àkọlé fídíò,

America Inauguration Joe: Wo àwọn eré orí ìtàgé tí Donald Trump ṣe kó tó fi ipò aàrẹ sílẹ̀

Mallam Adamu sọ pe lara nkan to tun wa ninu aba ofin naa ni idasilẹ eto owo iranwọ, àkànṣe owo ajẹmọnu fun awọn olukọ ti wọn ba gbe lọ si igberiko, to fi mọ awọn nkan idẹrun míì ti yoo mu ki isẹ naa ko wu awọn ọlọpọlọ pipe lati se.

Àkọlé fídíò,

US Vice President:Ẹ wo ìtàn obìnrin àkọ́kọ́ tí yóò jẹ igbákejì Ààrẹ ilẹ́ Amẹrika?