Kaduna Groom: Kí ló le mú kí àbúrò fẹ́ àfẹ́sọ́nà ẹ̀gbọ́n rẹ̀ níyàwó lẹ́yìn ikú rẹ̀ tí kò pé oṣù kan?

Oríṣun àwòrán, ADE RAHMAN
Iyawo, Hajara pẹlu afẹsọna rẹ to ku ni oṣu to lọ, Abubakar
"Ọkọ iyawo ma a wolẹ, ma a rọra, ẹyin iyawo ko ni i mẹni o".
Bayii gan-an lo ṣeeṣe ki wọn o maa ki Sulaiman Muhammad to gbe iyawo ọsingin, Hajara Ahmad, ni ogunjọ, oṣu Kẹta, ọdun 2021.
Lootọ ni iroyin ayẹyẹ igbeyawo ko jẹ tuntun, ṣugbọn nkan to mu ki igbeyawo yii jẹ ara ọtọ ni pe afẹsọna ẹgbọn rẹ to ku laipẹ ni Sulaiman fẹ niyawo
Iyawo afẹsọna ni Hajara jẹ fun ẹgbọn Sulaiman, Abubakar Muhammad, ọmọ ileeṣẹ ologun ofurufu to ku ninu oṣu Keji.
- Kí ló lè fàá kí Yomi Fabiyi àti PA rẹ̀ máa fẹnu ko ara wọn l'ẹ́nu?
- Ṣé ǹkan ọmọkùnrín rẹ ò ní padà kéré báyìí? Wo tuntun tí onímọ̀ Sáyẹ̀nsì gbéjáde
- Ayẹyẹ igbeyawo melo ni Aarẹ Buhari lọ?
- Wò ó bí Alaafin àti aya àkọ́fẹ́ rẹ̀, Olorì Abibat ṣe pàdé ní èwe
- Tẹgbọn-taburo se igbeyawo ni Anambra
- Wo ìgbéyàwó olówó iyebíye tí awakọ̀ Kabúkabú ti jẹ̀bùn ọkọ N3.4m
- Ọkọ'yàwó jẹ àjẹranjú ìyà lẹ́yìn tí ìyàwò rẹ̀ yọjú síbi ìgbéyàwó òun àti obìnrin mìràn
- L.ẹ́yìn tí wọ́n gba N100m àwọn ajínigbé tún lu Kábíyèsí bí ẹni lu bàrà - Olori Oba Imope
Bí Oduduwa Republic bá bẹ̀rẹ̀, a ò ní ṣe aburú fún àwọn tó takò wá, ìlànà ààtẹ̀lé rèé - Banji Akintoye
Asiko ti ikọ rẹ n ba awọn agbebọn ja ni ilu Birnin Gwari, nipinlẹ Kaduna, lo kagbako iku ojiji.
Lati ọjọ ti wọn si ti ṣe igbeyawo ni awọn eeyan ti n bu ẹnu atẹ lu u pe bawo ni eeyan ṣe maa fẹ afẹsọna ẹgbọn rẹ to ku lai tii ju oṣu kan lọ.
Oríṣun àwòrán, ADE RAHMAN
Sulaiman ati awọn to wa sibi ayẹyẹ igbeyawo naa. Sulaiman ni ẹni keji ni apa ọtun ninu aworan yii
Idi si niyii ti BBC fi kan si Sulaiman pe ki lo ri l'ọbẹ to fi waaro ọwọ.
Ohun to si sọ fun BBC ni pe lootọ ẹgbọn oun ti wọn bi oun tẹle ni Abubakar, ti oun si ni ifẹ rẹ pupọ.
"Iku rẹ ṣi jẹ ẹdun ọkan fun mi, amọ fifẹ ti mo fẹ iyawo afẹsọna rẹ ni bo ṣe jẹ."
O ṣalaye pe awọn ẹbi iyawo afẹsọna ọhun lo ranṣẹ si ẹbi awọn pe ọmọ wọn fẹ fẹ oun.
"Wọn ranṣẹ si wa pe Hajara sọ pe dipo ki wọn o fagile ayẹyẹ igbeyawo oun ati ẹgbọn mi ti ko le waye mọ nitori iku rẹ, o sàn ki n rọpo ẹgbọn mi gẹgẹ bi ọkọ.
"Bi ere, bi awada, emi ati ẹ ti di tọkọtaya bayii."
Ṣe Sulaiman ko ni iyawo afẹsọna tẹlẹ ni?
Ọgbẹni Sulaiman sọ fun BBC pe oun ni ọrẹbinrin ti oun n fẹ tẹlẹ, ṣugbọn kadara ni nkan to ṣẹlẹ yii, ati pe ọrẹbinrin oun ti gba kadara.
"Mo kuku ni ọrẹbinrin, ṣugbọn kadara ni nkan to ṣẹlẹ yii. Inu mi si dun pe ọrẹbinrin mi tẹlẹ ọhun gba kadara lori ọrọ naa. Nkan to ṣe pataki ju ni pe awọn ẹbi mejeeji faramọ nkan to ṣẹlẹ.
Oríṣun àwòrán, Ade rahman
Ọkọ iyawo, Sulaiman sọ pe ibukun Ọlọrun n bẹ lori igbeyawo naa
Ọkọ iyawo to jẹ oṣiṣẹ a bani ṣe ile loge(interior designer" nilu Kaduna sọ pe, oun ri diẹ lara nkan ti awọn eeyan n sọ lori ayelujara nipa igbeyawo naa, amọ ko ba oun ninu jẹ rara.
O ni ọrẹ oun kan lo pe akiyesi oun si nkan ti awọn eniyan n sọ, amọ ko ṣe nkankan lara oun nitori pe Ọlọrun ti sure fun igbeyawo naa.
"Ọlọrun ti sure fun igbeyawo wa, koda ojo rọ ni ọjọ ayẹyẹ naa, eyi to jẹ apẹẹrẹ ibukun Ọlọrun".