Sapara Williams: Agbẹjọ́rò ọmọ Nàíjíríà àkọ́kọ́ àti olóṣèlú tó dá bírà lásìkò ìjọbá amúnisìn

Sapara-Williams

Oríṣun àwòrán, litcaf.com

Arise ni arika, arika si ni baba iregun, ohun ti a ba se ni oni, ọrọ itan ni yoo da bo dọla, nitori naa lo se yẹ ka gbe ile aye se rere.

Awọn akọni ọmọ Yoruba to gbo ni ohun, ti itan n sọ rere nipa wọn nitori isẹ takuntakun ti wọn gbe se fun idagbasoke ilẹ Yoruba ati Naijiria lapapọ pọ lọ jantirẹrẹ.

Amọ ọkan gboogi lara wọn, ti itan aye rẹ jẹ manigbagbe ni Amofin Christopher Alexander Sapara Williams.

Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹgẹ bi a se ka loju opo ayelujara Wikepedia, Sapara Williams ni ọmọ Naijiria akọkọ ti yoo di amofin bo tilẹ jẹ pe awọn akọwe kan wa, ti wọn n sisẹ amofin nigba naa lai kẹkọ amofin.

Oríṣun àwòrán, Nigerianinfopedia

Itan aye Amofin Christopher Sapara Williams:

Ọjọ Kẹrinla, oṣu Keje, ọdun 1855 ni wọn bi Christopher Alexander Sapara-Williams.

Bo ti lẹ jẹ pe orilẹede Sierra Leone ni wọn bi i si, ọmọ Ijẹṣha ni orilẹede Naijiria ni baba rẹ.

Baba rẹ jẹ ọkan lara awọn ẹrú to gba ominira ni Sierra Leone, iya rẹ si jẹ ọmọ Ẹgba nilu Abeokuta.

Sapara Williams lọ si ileewe girama CMS nilu Eko, lẹyin naa lo lọ si Wesley College, Sheffield ni orilẹ-ede United Kingdom.

Imọ nipa ẹkọ ofin ni Sapara-Williams kọ nileewe Inner Temple, nilu London.

Ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 1879 si ni wọn gba a wọle gẹgẹ bi amofin nilẹ Gẹẹsi.

Oríṣun àwòrán, litcaf.com

Àkọlé àwòrán,

Sapara Willaims ati awọn agbẹjọro akẹẹgbẹ rẹ to jẹ alawọ̀ funfun

Eyi lo mu ko di agbẹjọro akọkọ to jẹ ọmọ Naijiria.

Ninu oṣu Kinni ọdun 1888 lo pada si Naijiria lati bẹrẹ iṣẹ gẹgẹ bi amofin, ilu Eko si lo ṣi ọfiisi rẹ si.

Gẹgẹ bi agbẹjọro, Sapara-Williams tayọ pupọ, o fi orukọ silẹ ni ile ẹjọ to gaju lọ ni Naijiria, gẹgẹ bi agbẹjọro akọkọ to jẹ ọmọ Naijiria.

Bakan naa lo jẹ Alaga ẹgbẹ agbẹjọro lọdun 1900 si 1915.

Bo tilẹ jẹ pe oun ni agbẹjọro akọkọ to jẹ ọmọ Naijiria, kii se oun nikan lo n ṣiṣẹ amofin lasiko naa.

Nitori aisi awọn agbẹjọro, titi di ọdun 1913 ni wọn n gba awọn ti kii ṣe amofin, amọ to ka iwe diẹ, to si ni imọ nipa ofin ilẹ Gẹẹsi, si iṣẹ agbẹjọro.

Lara awọn gbajugbaja ẹjọ to mojuto ni Cole vs Cole, agbẹjọro agba Gusu Naijiria ati ileeṣẹ John Holts.

Ko fi iṣẹ amofin rẹ mọ ni Naijiria, o tun ṣiṣẹ de orilẹ-ede Ghana.

Àkọlé fídíò,

Sunday Igboho: Femi Falani ní ẹjọ́ Igboho ní Cotonou ń kọ́ àwọn amòfin Nàíjíríà ní ẹ̀kọ́

Sapara-Williams daba pe ki ilẹ Yoruba wa labẹ isakoso kan soso bii orilẹede

Iṣẹ amofin nikan kọ ni Sapara-Williams mojuto, o tun ko ipa pataki ninu ọrọ oṣelu Naijiria lasiko iṣakoso awọn oyinbo amunisin.

Lọdun 1904, itan sọ pe Sapara-Williams gẹgẹ bi ọmọ ile aṣofin, daba pe ki wọn o ṣatunto alaafo to wa laarin ẹkun Ariwa ati Gusu Naijiria.

Ọna to ni ki wọn gbe e gba ni pe ki wọn ko gbogbo awọn eeyan to n sọ ede Yoruba papọ wa si Gusu, labẹ iṣakoso kanṣoṣo, tii see orilẹede kan lọtọ.

Amọ ṣa, Lord Lugard tako aba naa, pẹlu awawi pe iṣakoso naa ko ni rọrun, ati pe ero awọn eniyan yoo yatọ.

Ipa kekere kọ ni Sapara-Williams ko lọdun 1914 nigba ti Lord Lugard so Guusu ati Ariwa pọ di orilẹ-ede Naijiria.

Àkọlé fídíò,

Ọ̀pẹlọpẹ́ Ajá tí Ifa ní kí a fi ṣètùtù ní Ekiti ní 1942 ni kò jẹ́ kí ìjàmbá náà pọ̀ jù- Ol

O jẹ ọkan lara awọn ọmọ ile aṣofin lasiko naa, ile aṣofin naa lo si wa lati ọdun 1901 titi di ọdun 1915 to kú.

Lọdun 1905 , o ṣabẹwo si ilẹ Gẹẹsi. Nigba to wa ni ibẹ, o daba fun awọn alaṣẹ to n mojuto imunisin lati ṣe ayipada si awọn ilana ti wọn fi n dari.

Lara awọn aba to da fun wọn ni idasilẹ ile ẹkọ awọn olukọ nilu Eko.

Yatọ si eyi, o tun tako ofin ọdun 1909, ti ko faaye gba awọn oniroyin lati bu ẹnu atẹ lu ijọba.

O ni "iru ofin yii ko si ninu iwa ati iṣe awọn Yoruba, bẹẹ ni ko si ba ofin wọn mu".

Ṣugbọn o ṣe ni lanu pe, bo ṣe bẹbẹ to, awọn oyinbo amunisin papa sọ aba naa di ofin.

Àkọlé fídíò,

Tunde Bakare journey in life: Bàbá bàbá mi ni Lèmọ́mù àkọ́kọ́ ní Sodeke Abeokuta ṣùgbọ́n..

Sapara William se agbelarugẹ ijo Egungun lai fi ti ọlaju rẹ se:

Bi o tilẹ jẹ pe ọlaju, ọmọwe ati amofin to dantọ ni Sapara Williams, sibẹ o si se agbelarugẹ awọn asa ilẹ Yoruba laye awọn eebo amunisin.

Williams, ẹni to gbagbọ pe amofin gbọdọ maa lọ sibi ti awọn eeyan rẹ ba n lọ ni, se onigbọwọ ijo egungun losu kẹwa ọdun 1896.

Inu gbogbo awọn ọba alaye nilẹ Yoruba nigba naa si lo dun si igbesẹ yii nitori pe ko tiẹ naa ni pe gbajumọ ati alakọwe ni oun.

Sapara Williams ki aye pe lọdun 1915:

Bi Sapara Williams se yaayi to yii, to si n sisẹ takuntakun fun ilọsiwaju iran Yoruba, amọ kokoro ko jẹ ka gbadun obi rẹ to gbo kaka.

Iku sadede ja okun ẹmi akikanju, akọ niwaju adajọ agbẹjọro yii pati, ti iku si pa oju rẹ de ni ẹni ọgọta ọdun.

Ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹta, ọdun 1915 ni Christopher Alexander Sapara-Williams ki aye pe o digbose.

Àkọlé fídíò,

Oba Gbolahan Timson shomolu: Obasanjo ti jẹ́wọ́ pé 'Mistake' ni Buhari ṣùgbọ́n...

Ẹkọ ti itan aye Christopher Sapara Williams kọ wa:

Itan aye Sapara Williams kọ wa lati nifẹ ilẹ baba wa, ka si maa wa ilọsiwaju ati idagbasoke rẹ.

O tun kọ wa pe ka maa gbiyanju lati tayọ awọn eeyan yoku to saaju wa ninu ohun gbogbo ta ba dawọ le gẹgẹ bi Williams se kawe amofin saaju awọn eeyan miran to n sisẹ amofin.

Itan yii tun kọ wa pe ka ni igboya, ọkan akin ati aayan lati maa sọrọ soke paapaa niwaju awọn eeyan to ni ẹru ati alasẹ, gẹgẹ bi Sapara Williams ti se niwaju awọn eebo amunisin.

Lakotan itan igbe aye Sapara Williams kọ wa lati maa gbe asa wa larugẹ lai naani ba se laju to tabi kawe to bi Williams ti se lati se agbelarugẹ ijo egungun, tii se ara asa ilẹ Yoruba.